Monisọla Saka
Igbakeji oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Datti Baba-Ahmed, ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari, ati adajọ agba ilẹ Naijiria, Olukayọde Ariwoọla, lati ma ṣe ṣe ayẹyẹ ibura wọle sipo aarẹ fun aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Tinubu, eyi ti yoo waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, nitori ijawe olubori ẹ gẹgẹ bii aarẹ tuntun, ko wa ni ibamu pẹlu ofin ilẹ Naijiria.
Lasiko to n sọrọ lori tẹlifiṣan Channels nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, Datti ni ẹgbẹ oṣelu APC ko tẹlẹ abala kẹrinlelaaadoje iwe ofin ilẹ wa lori didibo wọle sipo aarẹ. O ni gẹgẹ bi ohun to wa ninu iwe ofin ọhun, eeyan to lẹtọọ sipo aarẹ ni ẹni to ba ni ibo to pọ ju lọ lasiko idibo, ati pe iru ẹni bẹẹ gbọdọ ni ibo to to to ilarin ni bii ida meji ninu mẹta ibo gbogbo ipinlẹ lorilẹ-ede yii, ati niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ Naijiria.
Datti ni pẹlu alaye toun ṣe kalẹ yii, ko wa ni ibamu pẹlu ofin Naijiria, ti wọn ba duro lori pe wọn yoo bura fun Tinubu.
O ni, “Aarẹ wa, ẹ ma jẹ ki ayẹyẹ ibura wọle yẹn waye, Oluwa mi, ẹ jọọ, ẹ ma lọwọ ninu ohun ti ko bofin mu.
Ohun ti emi tumọ abajade eto idibo yẹn si niyi, ohun to si tọna naa niyẹn. Ẹ o le bura fẹni ti ko ṣe gbogbo nnkan ti ofin la kalẹ, ẹ o le ṣe bẹẹ. Tẹ ẹ ba waa ṣe bẹẹ, ẹ ti ṣe nnkan to ta ko ofin, nnkan ti ko wa ni ibamu pẹlu ofin, ẹ ti tẹ ofin loju mọlẹ niyẹn. Aṣeju ati iwanwara ni bi alaga ajọ INEC, Mahmood Yakubu, ṣe lọọ gbe iwe-ẹri ẹni to wọle ibo aarẹ le Tinubu lọwọ, iwa aibikita si ni pẹlu. O n fi ẹmi gbogbo wa wewu ni o”.
Datti tẹsiwaju pe, ti wọn ba ṣe ayẹyẹ ibura fun Tinubu gẹgẹ bii aarẹ ilẹ Naijiria tuntun, lai jẹ pe iru ẹni bẹẹ ti ṣe gbogbo ohun ti ofin wi, a jẹ pe wọn fẹẹ fopin si ijọba awa-ara-wa ni.
Ka ranti pe lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti kede oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Tinubu, gẹgẹ bii aarẹ tuntun, lẹyin ti wọn ni oun lo gbegba oroke ninu ibo aarẹ ti wọn di lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.