Monisọla Saka
Aarẹ ilẹ Naijiria tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti bu ẹnu atẹ lu oniruuru iwa janduku to ṣẹlẹ jake-jado orilẹ-ede Naijiria lasiko eto idibo mejeeji to waye, iyẹn ibo aarẹ to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ati tawọn gomina to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Tinubu sọrọ yii ninu atẹjade to fi sori ẹrọ ayelujara eto ipolongo ibo oun ati Shettima, o waa rọ awọn ọmọ Naijiria lati fa ara wọn mọra, ki wọn si fimọ ṣọkan, lai wo ti gbogbo iwa ẹlẹyamẹya to waye lasiko idibo.
O ni, “Pẹlu bi eto idibo gomina ati tawọn aṣofin ipinlẹ ṣe kasẹ nilẹ yii, mo ki awọn gomina tuntun atawọn aṣofin tuntun ku oriire fun bawọn eeyan ṣe gbe agbara le wọn lọwọ. Eto idibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn ipinlẹ mejidinlọgbọn ati tawọn aṣofin to waye jake-jado orilẹ-ede yii, ti mu eto idibo ọdun 2023 wa sopin.
Amọ ṣa o, inu mi ko dun pẹlu iroyin iwa ẹlẹyamẹya ti wọn lo waye lasiko idibo ati lẹyin ti wọn pari ẹ lawọn ipinlẹ kan. Mo koro oju si iwa naa, bẹẹ naa ni ọrọ ile atawọn nnkan mi-in ti wọn n mọ-ọn-mọ dana sun lẹyin ti wọn kede esi idibo gomina nipinlẹ kan, eyi ko ṣafihan iru eeyan ta a jẹ rara, nitori eeyan kan to nifẹẹ alaafia ni wa.
“Gbogbo awọn ọrọ alufanṣa, ati bi wọn ṣe n lu awọn eeyan ko le jẹ itẹwọgba, bẹẹ ni ko wa ni ibamu pẹlu ijọba awa-ara-wa.
Ajọyọ ominira ati ijọba awa-ara-wa lo yẹ ki eto idibo jẹ, ko yẹ ko jẹ asiko ibanujẹ fun wa. Ọrọ ẹlẹyamẹya yẹn lo ka mi lara ju, nitori eleyii le da wahala nla, iru awọn eyi ti wọn lo ṣẹlẹ lapa ibi kan silẹ.
Mo wa n rọ wa pe ka jọọ, ka pa ọrọ apa ibi ti onikaluku ti wa ti, ka si fọwọsowọpọ lai wo ti ẹya tabi ede wa”.
Tinubu tẹsiwaju pe, gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri, oun le sọ bi iṣọkan ṣe jọba laarin wa to. O ni gẹgẹ bii aarẹ ilẹ Naijiria tuntun, ọrọ ajọṣepọ to fẹsẹ mulẹ nipinlẹ Eko yẹn gangan loun fẹẹ fi ṣe atẹgun ijọba oun, ki ajọṣepọ wa le mu igbega ba orilẹ-ede yii. Bakan naa lo tun ṣeleri pe oun yoo pese ayika ti yoo fawọn eeyan lanfaani lati dibo yan ẹni to wu wọn lai si ifoya.
Tinubu ni, gẹgẹ bii adari ti wọn dibo yan, ojuṣe koowa awọn ni lati sin awọn eeyan ti wọn gbe awọn depo, lati lọọ ṣoju wọn, o ni ki gbogbo wọn ṣiṣẹ takuntakun lati le mu aye dẹrun fawọn araalu. O tun gba wọn nimọran lati ṣiṣẹ tọ bi iṣọkan yoo ṣe wa laarin awọn eeyan, atawọn ti wọn dibo fun wọn, atawọn ti wọn ko di. O ran wọn leti pe asiko oṣelu ti lọ, iṣẹ bi orilẹ-ede yoo ṣe goke agba lo ku. Tinubu waa fi wọn lọkan balẹ pe oun gẹgẹ bii aarẹ ti ṣetan lati ṣiṣẹ papọ pẹlu wọn, lati le jẹ ki Naijiria daa ju bayii lọ.