Awọn oluwọde bẹ Buhari: Ẹ gbe ijọba fidi-hẹ ti yoo ṣeto idibo tuntun dide

Ọrẹoluwa Adedeji

Ariyanjiyan to n lọ lori eto idibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ko ti i rodo lọọ mumi rara. Eyi ko sẹyin bi awọn ẹgbẹ kan ti wọn pera wọn ni National Youth League for Defence of Democracy (NYLDD), ti wọn ṣewọde niluu Abuja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii. Lara ohun ti wọn n beere, ti wọn si tori rẹ ṣewọde naa to bẹrẹ ni Unity Fountain,  ni pe ki ijọba Buhari ṣeto ijọba fidi-hẹ ko too kuro lori ipo, ko si paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ nilẹ wa (DSS), fọwọ ofin gbe Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa, Mahmood Yaqub kuro nipo rẹ.

Nigba to n sọrọ lorukọ ẹgbẹ naa, Dokita Moses Paul, sọ pe ijọba fidi-hẹ tawọn n beere fun yii ni yoo yan alaga eleto idibo mi-in, ti yoo si ṣeto idibo tuntun ti awọn araalu yoo fi yan aarẹ to yẹ fun orileede yii.

Bakan naa ni wọn bẹ ileeṣẹ ilẹ Amẹrika to wa ni Naijiria, iyẹn United State Embassy Consulate, pe ki wọn jọwọ, ki wọn gba iwe irinna ilẹ Amẹrika ti wọn fun Mahmood, ati gbogbo awọn alaga ajọ eleto idibo awọn ipinlẹ bii Zamfara, Eko, Rivers, Borno, Niger, Jigawa, Kano, Imo, Ebonyi, Ekiti, Ogun ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti awọn wahala ati fifi ẹtọ ẹni du ni lati dibo yii ti waye.

Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe, ‘‘Koko nnkan meji la n beere fun. Akọkọ ni pe ki wọn fọwọ ofin mu Alaga eleto idibo ilẹ wa, Mahmood Yaqoob, ki wọn si ba a ṣẹjọ. O nilo ki wọn mu Mahmood, ẹni to hu iwa jibiti to buru ju ninu itan iran eeyan, ki wọn si ba a ṣẹjọ.

‘‘Ibeere wa keji ni ki wọn gbe ijọba fidi-hẹ dide. A n sọ eleyii nitori a ko fẹ ki Aarẹ Buhari tẹsiwaju lori ipo, gẹgẹ bii baba, a fẹ ko ṣeto ijọba fidi-hẹ. Ijọba fidi-hẹ yii ni yoo waa yan alaga ajọ eleto idibo mi-in ti yoo ṣeto idibo tuntun to maa waye, ti ko ni i ni eru tabi jibiti ninu, ti wọn yoo si le yan aarẹ to poju owo fun wa.

‘‘Ọmọ orileede Naijiria ni wa, olufẹ orileede yii ni wa pẹlu, a si n tọ ilana ofin ati ẹtọ wa gẹgẹ bii ọmọ orileede. A wa lati sọrọ nipa iwa ọdaran to buru ju ninu itan gbogbo agbaye to waye ni Naijiria. Wọn dana sun ọpọ eeyan ni Kano, wọn yinbọn pa awọn eeyan ni Rivers, ohun ti wọn si foju awọn eeyan ri nipinlẹ Eko lori eto idibo yii ko ṣee fẹnu sọ.

A wa sibi yii gẹgẹ bii ọmọ Naijiria ti gbogbo rẹ ti su, ati lati fehonu han lori bi Alaga ajọ eleto idibo, Yaqub Mahmood ṣe fi ẹtọ awọn ọmọ orileede yii du wọn. Idi niyi ti a fi n pe fun pe ko kọwe fipo silẹ loju-ẹsẹ, ki ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa si fọwọ ofin gbe e, ki ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ wa, (EFCC) si wadii rẹ. Bakan naa la n beere fun idajọ ododo lati ọdọ awọn adajọ ilẹ wa pẹlu bi awọn ti ọrọ kan ṣe ti gba kootu lọ lati gba ẹtọ wọn pada.

‘‘A ti lọ si Ẹmbasi awọn Amẹrika, a ti lọ si ti British Coouncil to wa ni Naijiria, bẹẹ la si ti kọwe ranṣẹ si awọn aṣoju ilẹ France, to wa lorileede wa. A ti sọ fun wọn ki wọn gba ijọba Naijiria nimọran, nitori inu awọn ọmọ orileede yii ko dun si ohun to n lọ nilẹ wa. A le jẹ eeyan alaafia loootọ o, ṣugbọn bi wọn ba sun ewurẹ paapaa kan ogiri, dandan ni ko paju da.

Oriṣiiriṣii patako pẹlu ọkan-o-jọkan akọle ni wọn gbe lọwọ pẹlu awọn ọrọ ti wọn kọ sibẹ pe, ‘Iwa ọdaran ni fifi ẹtọ awọn oludibo du wọn’,  ‘A mọ ẹni to wọle idibo’ ‘Ti a ba gba eto idibo ọdun 2023 yii wọle, bawo la ṣe fẹẹ sọ fun awọn adigunjalẹ ati awọn ajinigbe pe ohun ti wọn n ṣe ko dara’ ‘Idajọ ododo la n wa, a ja fun Naijiria tuntun’’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Reply