Ramadan: Oyetola rọ awọn Musulumi lati tubọ sun mọ Ọlọrun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti ba awọn Musulumi kaakiri ipinlẹ Ọṣun ati kaakiri agbaye yọ lori oṣu aawẹ lamulaana to wọle de.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Oyetọla, Ismail Omipidan, fi sita lo ti rọ awọn Musulumi gbogbo lati lo asiko naa lati fi tun igbagbọ wọn ṣe, ki wọn si sun mọ Ọlọrun si i.

O ni pataki oṣu mimọ naa ni lati jẹ pipe niwaju Ọlọrun Allah, awọn Musulumi si gbọdọ ṣafihan ifẹ, ipamọra, aanu ṣiṣe, iyọnusi, ki wọn si maa gbe igbe aye alaafia pẹlu eniyan gbogbo.

Oyetọla ṣapejuwe oṣu Ramadan gẹgẹ bii oṣu ibunkun, aanu ati idariji ẹsẹ latọdọ Allah, o waa ke si awọn Musulumi nipinlẹ Ọṣun lati fi asiko naa gbadura fun idagbasoke ati alaafia pipe kaakiri orileede Naijiria.

Oyetọla tun gbadura fun ilera to peye fun gbogbo awọn Musulumi ododo lati le gba aawẹ naa, ki wọn si le ṣe gbogbo ojuṣe inu rẹ.

Leave a Reply