Bi Ọlọrun ṣe yọ ọgọrin eeyan n’Ijọra Badia ree o, diẹ lo ku ki ile wo pa wọn

Aderounmu Kazeem

Eeyan bi ọgọrin atawọn ọmọde bii aadọta lori ko yọ lasiko ti ile alaja kan da wo lulẹ ni Badia Ijọra l’Ekoo.

Ohun ta a gbọ ni pe, ṣaaju ki iṣẹlẹ ọhun too waye ni ile naa to wa lojule kẹrindinlọgbọn, popo Afọlabi Alasia, ti n fi sẹgbẹẹ, ko too wo lulẹ lanaa.

Yara bii ogun ni won sọ pe o wa ninu ile ọhun, ati pe lojiji ni apa kan lọwọ ẹyinkule ile naa ya lulẹ, ti kaluku si bẹrẹ si sare asala fun ẹmi wọn ki gbogbo ẹ too wo patapata.

Lojuẹsẹ tisẹlẹ ọhun waye ni awọn ajọ eleto aabo atawọn agbofinro loriṣiriṣii ti debẹ lati pese aabo to yẹ.

Ninu ọrọ ti ọga agba fun ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo, (Lagos State Emergency Management Agency) sọ lo ti ṣalaye pe eeyan mọkandinlọgbọn lori ko yọ, ninu eyi ti mẹẹdogun ti jẹ ọkunrin, ti eeyan mẹrinla si jẹ obinrin pẹlu awọn ọmọ keekeeke bii mejidinlaadọta.

 

Leave a Reply