Mo n fi ibọn tawọn Amọtẹkun ba lọwọ mi daabo bo ara mi ni-Reuben

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ẹṣọ Amọtẹkun Ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun marundilogoji kan, Monday Reuben, pẹlu ibọn ilewọ pelebe ti wọn ka mọ ọn lọwọ ninu igbo kan ni Isẹ-Ekiti, nijọba Ibilẹ Isẹ/Ọrun.

Bakan naa ni ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun tun tẹ ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun mi-in Akanbi Emmanuel, pẹlu ọgbẹ́ ati ifarapa ti wọn fura si po ọgbẹ ibọn ni.

Ọga awọn ẹṣọ naa nipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ lakooko to n ṣe afihan awọn afunrasi naa pe nibi ti Reuben da oko igbo si ninu aginju igbo kan ni Isẹ-Ekiti, lọwọ awọn ti tẹ ẹ pẹlu ibọn ilewọ agbelẹrọ kan.

Kọmọlafe ni adugbo Oke-Ila, ni Ado-Ekiti, lawọn ti mu afurasi kan to ku, lẹyin tawọn araalu ta awọn lolobo pe inu aginju igbo Isẹ-Ekiti lo ti gbe ọgbẹ naa jade, ati pe oju ọgbẹ ibọn ni.

Nigba ti wọn n fi ọrọ wa a lẹnu wo, afurasi naa jẹwọ pe lati inu igbo Ọwọ, nipinlẹ Ondo loun ti wa si agbegbe naa, ati pe agbẹ to nda oko igbo ni oun, o ni oko igbo loun waa da ninu aginju naa.

O ni oun n fi ibọn ilewọ naa daabo bo ara oun ni, pẹlu bi awọn darandaran ṣe n da oun laamu ninu igbo naa, ti wọn si n ba oko igbo oun jẹ.

Nipa ti afurasi ti oju ọgbẹ ibọn wa lara rẹ, Kọmọlafe ṣalaye pe ni kete ti awọn araalu ta awọn lolobo lawọn bẹrẹ iwadii lori bi awọn yoo ṣe ri i mu pẹlu oju ọgbẹ ibọn naa.

O fi kun pe ojuṣe ẹṣọ Amọtẹkun ni lati jẹ ki gbogbo eeyan ilu mọ boya afurasi naa lọọ jale, ti wọn si yin in nibọn ni. O fi kun un pe iwadii ti n tẹsiwaju lori ọrọ naa. O ni wọn yoo taari awọn ọdaran naa si awọn ọlọpaa ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ wọn.

Ọga Amọtẹkun naa rọ awọn araalu pe ki wọn maa fi oju sode, ki wọn si maa fi to awọn leti ti wọn ba ti kẹẹfin awọn ọdaran nitosi wọn. Bakan naa lo kìlọ fun awọn ọdaran lati tọwọ ọmọ wọn bọṣọ.

Leave a Reply