Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Gbogbo awọn to gbọ ọrọ ọmọkunrin kan, Wasiu Mukaila, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti ko ri ibomi-in jale mọ to ju kootu lọ ni wọn n sọ pe ki ẹwọn rẹ le ya kankan lo fi ṣe bẹẹ.
O si ti gba idajọ ẹọn loootọ, nitori l’Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii, ni Onidaajọ Hafusat Alegẹ paṣẹ pe ki wọn lọọ ju ọdaran naa sẹwọn ọdun meji pẹlu iṣẹ asekara lori ẹsun pe o ji ọkada gbe ninu ọgba ile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Awọn ọlọpaa sọ pe wọn ti kọkọ mu Mukaila fẹsun pe o ji ọkada gbe, eyi ti ọn n tori rẹ ba a ṣejọ ni kootu naa. Nigba ti ẹlẹgiri tun de inu ọgba kootu ti wọn ti n ba a ṣẹjọ ọhun lo ba tun ri ọkada mi-in to wọ ọ loju, n lo ba tun ki i mọlẹ, o gbe e lọ, ṣugbọn ọwọ pada tẹ ẹ, o si mu awọn agbofinro lọ sọdọ ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Ahmadu Dan Asebe, ẹni to ta ọkada naa fun. Ni wọn ba tun wọ ọ wa siwaju adajọ.
Agbefọba sọ fun kootu pe iwadii fihan pe iṣẹ ti Mukaila yan laayo ni ko maa ji ọkada gbe nigboro ilu Ilọrin ati agbegbe rẹ. Nigba ti wọn beere lọwọ re boya o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an abi ko jẹbi, afurasi ọdaran naa ni loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Onidaajọ, Hafusat Alegẹ gba beeli Asebe, ẹni to ra ẹru ole naa, ṣugbọn o paṣẹ pe ki wọn sọ Mukaila sẹwọn ọdun meji gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.