Ẹgbẹ Labour fẹẹ da owo fọọmu oludije wọn to ku lojiji pada fawọn mọlẹbi rẹ

Monisọla Saka

Alaga apapọ fẹgbẹ oṣelu Labour Party, Julius Abure, ti sọ pe ẹgbẹ awọn ti ṣetan lati da miliọnu mẹẹẹdọgbọn Naira, ti i ṣe owo ti ọkan ninu awọn oludije funpo gomina nipinlẹ Imo, Humphrey Anumudu, to ti doloogbe fi ra fọọmu dupo gomina pada fawọn ẹbi ẹ.

Anumudu to ra fọọmu yii lati dije funpo gomina ipinlẹ Imo, ninu ibo abẹle ẹgbẹ wọn ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lo jade laye nile ẹ to wa niluu Eko lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Ninu ọrọ ẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, Abure ni ẹgbẹ ti n gbe igbesẹ lati da owo fọọmu naa pada fawọn mọlẹbi oloogbe, lati le fi imọlara wọn han lori iku ọkan ninu wọn yii.

O ni, ” Ẹ oo ranti pe ọkan ninu awọn oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ wa nipinlẹ Imo, padanu ẹmi rẹ lọsẹ to kọja.

Inu mi dun lati kede fawọn araalu ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ Labour Party, to fi mọ awọn mọlẹbi oloogbe, pe ẹgbẹ yoo da owo fọọmu to ra ko too dagbere faye pada fawọn mọlẹbi rẹ”.

O lawọn ro pe eleyii ṣe pataki lati le fi atilẹyin han si mọlẹbi, ati lati fi oju aanu han si wọn, nitori oju aanu ati ifẹ ọmọniyan lọkan  ni ohun ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party duro fun.

Leave a Reply