Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ṣe owe Yoruba kan lo sọ pe ebi ki i wonu kọrọ mi-in wọ ọ, ti wọn si tun ni okun inu la fi n gbe tode. O jọ pe eyi ni iyaaale ile kan, Awau AbdulRazaq, ro papọ to fi ni oun ko fẹ ọkọ oun, AbdulRazaq Ayinde mọ, o ni ebi buruku ni ọkunrin naa fi n pa oun ati awọn ọmọ oun, ko si bikita nipa awọn ọmọ, ẹmi oun ko si gbe e mọ. Lo ba rawọ ẹbẹ si adajọ pe ki won jọwọ jare tu igbeyawo naa ka, ki onikaluku maa lọ lọtọọtọ.
Kootu kọkọ-kọkọ kan to fikalẹ sagbegbe Ìpàta Ọlọ́jẹ̀, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lobinrin yii gbe ọkọ rẹ lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ oṣu Kẹta, ọdun yii.
Olupẹjọ naa, Awau, sọ niwaju adajọ kootu ọhun pe lati bii ọdun mẹrin sẹyin lọkọ oun ko ti fowo ounjẹ silẹ, bẹe ni ko si ra ounjẹ silẹ toun atawọn ọmọ le jẹ, debi ti yoo sanwo ileewe wọn.
Iyaale ile yii ni lasiko ti ọkan ninu awọn ọmọ oun fẹ ṣe Saada kuraani nileekewu, ọkọ oun ko fi Naira kan lo kere ju silẹ, nigba toun si beere owo lọwọ rẹ, o ni oun kọ loun fi ọmọ sile kewu.
O ni bi oun ba n ṣe aisan, ọkọ oun ki i tọju oun, fun idi eyi, ki ile-ẹjọ pin awọn niya.
Awau ni, ‘Ọmọ marun-un ni mo bi fun un, mẹta lo n gbe pẹlu mi bayii, meji si n gbe pẹlu ọkọ mi, mi o si le fawọn ọmọ mi silẹ sakata ẹ, ẹ ṣaa ba mi pa a laṣẹ pe ko maa gbọ bukaata awọn ọmọ ẹ’’.Obinrin yii ni oun yoo gba ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000), gẹgẹ bii owo ajẹsilẹ toun fi n tọ awọn ọmọ lati bii ọdun mẹrin sẹyin. Bakan naa lo ni oun yoo maa gba ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (50,000), loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounjẹ, owo ileewe ati iwo itọju nigbakuugba tawọn ọmọ naa ba ṣaisan.
Nigba to n wi awijare tirẹ, ọkọ Awau to jẹ olujẹjọ, AbdulRazaq, sọ fun ile-ẹjọ pe oun ko ṣetan lati kọ iyawo oun, ati pe oun ko ni owo kankan ti oun yoo maa fun iyaale ile naa, o ni to ba ti mọ pe oun fẹẹ kọ oun silẹ, ko ba oun ko awọn ọmọ oun ki oun maa tọju wọn.
Onidaajọ Ajibade Lawal beere lọwọ ọkọ pe lọjọ wo lo ti fun iyawo atawọn ọmọ lowo ounjẹ gbẹyin, “o n fi ebi pa iyawo atọmọ, o waa sọ pe ka ma tu igbeyawo yin ka”. Ọkọ dahun pe yoo ti to ọdun kan pẹlu alaye.
Adajọ Ajibade Lawal paṣẹ pe ki ọkunrin naa fun iyawo rẹ ni ẹgbẹrun mẹwaa Naira (10,000), loju-ẹsẹ gẹgẹ bii owo ounjẹ tabi ko lọọ sun atimọle.
Lẹyin aṣẹ ti adajọ pa yii lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹwaa, oṣu karun-un, ọdun 2023 yii.