Monisọla Saka
Gomina Bello Matawalle ipinlẹ Zamfara, ti di ẹbi bi ipo gomina ṣe bọ sọnu lọwọ ẹ sọwọ awọn alatako le Aarẹ Muhammadu Buhari ati ipaarọ owo Naira lori.
Matawalle to sọrọ yii lasiko to n ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ikanni DW Hausa, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023, sọrọ yii lasiko to n ṣalaye bo ṣe padanu ibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Matawalle to n dupo gomina ipinlẹ Zamfara fun saa keji labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn to padanu ipo naa sọwọ Dauda Lawal, ti i ṣe ojugba rẹ lẹgbẹ PDP, ṣalaye lasiko to n sọ si ọrọ esi idibo pe apọju awọn ọmọ ogun ti wọn ko wa lọjọ idibo lo bẹgidina ati-wọle oun fun saa keji.
O lawọn ileeṣẹ ologun ko awọn ṣọja bii ilẹ bii Ọlọrun wa sipinlẹ Zamfara, nitori eto idibo, bo tilẹ jẹ pe wọn ko gbe igbesẹ lati koju eto aabo to dẹnu kọlẹ nipinlẹ naa, pẹlu bi ijọba oun ṣe rawọ ẹbẹ sijọba Buhari lati wa nnkan ṣe si i to.
O ni, “Mo kilọ fawọn eeyan mi lati ma ṣe yi ibo nitori mi. Mo fẹ kawọn eeyan dibo fun mi lati ọkan wọn wa ni, mo si fẹ ki erongba awọn araalu wa si imuṣẹ.
Ṣugbọn iru awọn ṣọja ti wọn ko wa fun ibo yẹn lagbara pupọ. Awọn ologun to pọ to bayii o ti i wọ ipinlẹ yii wa ri. Bi mo ṣe ti ri i bayii, mo mọ pe nnkan mi-in wa ninu ọrọ ọhun, nitori bẹẹ ni mi o si ṣe jampata. Ọrọ kan ti kọkọ to mi leti tẹlẹ labẹ aṣọ pe wọn fẹẹ fiya jẹ emi, Gomina Nasir El-Rufai Kaduna, ati Abdullahi Ganduje ti ipinlẹ Kano ni.
“Wọn ni ẹṣẹ ta a ṣẹ ni pe a n ta ko ijọba nile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ yii, Supreme Court, nitori ọrọ owo Naira. A ti n ba ọrọ eto aabo ti ko fara rọ lawọn ipinlẹ yii, ọjọ ti pẹ, ta a si ti n bẹbẹ fun iranlọwọ titi, ṣugbọn a ko rẹni da wa lohun. Ọjọ idibo wa n ku si dẹdẹ, ẹ kọ awọn ọmọ oju ogun to le ni ọọdunrun wọ ipinlẹ yii wa”.
Pẹlu bi agbara ṣe ti bọ lọwọ ẹ naa, gomina yii ni o dun mọ oun ninu nitori awọn iṣẹ ribiribi toun gbe ṣe nipo lati bii ọdun mẹrin sẹyin. Bẹẹ lo tun fi kun un pe oun ko raaye ile-ẹjọ ni lilọ, nitori ati le ja fun esi idibo ọdun 2023 to gbe ẹgbẹ alatako wọle ọhun.
O tun tẹsiwaju pe, “Eto idibo ti pari, gbogbo eeyan lo ri nnkan to ṣẹlẹ ni Zamfara, ṣugbọn gẹgẹ bii Musulumi, ọpẹ nikan naa ni mo le maa da fun Ọlọrun pẹlu abajade esi idibo naa.
Nigba t’Ọlọrun gbe mi depo, ọpọlọpọ eeyan ni ko ro pe mo le di gomina ipinlẹ naa, Ọlọrun si ṣe e fun mi. To ba tun waa fẹẹ gba a pada lọwọ mi, mi o le bi i lẹjọ. Ọlọrun ti kọ ọ pe saa kan naa ni mo maa ṣe, mo dẹ ti gba bẹẹ.
O ni lati ọjọ pipẹ ni ọrọ ipo naa ti su oun latari gbogbo awọn iṣẹlẹ to n waye nipinlẹ naa. O loun gbiyanju gbogbo agbara oun lati koju iṣoro eto aabo to ti dẹnu kọlẹ, ṣugbọn to jẹ pe o kọja agbara oun, ati pe Ọlọrun nikan lo le fopin si i.