Obinrin to gun ọkọ rẹ lọbẹ pa ti dero ẹwọn, wọn lo larun ọpọlọ ni

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki obinrin alaaganna kan, Janet Jẹgẹdẹ, maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn to wa lopopona Afao-Ekiti, titi digba ti ijọba yoo fi pese ibi itọju to peye fun un.

Obinrin were naa to jẹ nọọsi nileewosan ijọba kan l’Ado-Ekiti, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, lo ṣeku pa ọkọ ẹ, Ọgbẹni Kayọde Jẹgẹdẹ, sinu ile wọn to wa laduugbo Baṣiri, l’Ado-Ekiti, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, wọn ni obinrin yii ni gan-an-gan-an-gan-an lori,  to si ti n gbe pẹlu ọkọ ẹ to pada ṣeku pa ọhun lati bii ọdun mẹfa sẹyin.

ALAROYE gbọ pe aisan yii de si i lẹyin ọdun karun-un to ṣegbeyawo pẹlu ọkọ ẹ to doloogbe yii.

Wọn ni ọkunrin naa ti na gbogbo owo to ni lori aisan iyawo ẹ yii, ṣugbọn aisan ọhun ko gbọ. Wọn ni lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2019, ni obinrin yii sadeede fa ọbẹ yọ, to si gun ọkọ ẹ yii ni ọọkan igbaaya rẹ ninu yara wọn ni kutukutu aarọ ọjọ naa.

Gẹgẹ bi ọmọ oloogbe naa to tun jẹ ọmọ orogun obinrin alaaganna yii, Ayọmide Jẹgẹdẹ, to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun ṣe sọ, o ni lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ṣadeede loun gba ipe lati ori ẹrọ ilewọ oun lati ọdọ orogun iya oun yii. O ni koun maa bọ nile lati waa gbe baba oun lọ sileewosan, nitori pe oun ti fẹẹ pa a.

Ayomode sọ pe logan loun pada sile, ṣugbọn obinrin naa ti mu ileri rẹ ṣẹ koun too dele, nitori ninu agbara ẹjẹ loun ba baba oun, nibi to ti n japoro iku, toun si tun ri ọbẹ to fi gun un to ṣi wa nigbaaya rẹ nibẹ.

O ni gbogbo alaye toun beere lọwọ baba oun lori bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ lo ja si pabo pẹlu bi ko ṣe le sọrọ kankan foun. O ni b’oun ṣe fa ọbẹ to wa laya baba oun yọ ni ẹjẹ naa tun bẹrẹ si i tu sita. Ayọmide ni oju-ẹsẹ loun pe gbogbo awọn araadugbo, ti wọn si ba oun gbe e lọ sileewosan ijọba ni Ado-Ekiti, nibi ti awọn dokita ti sa gbogbo ipa wọn lati le ji i pada, ṣugbọn o ti jade laye.

Ayomide ni obinrin alaaganna yii ti sọ foun pe ki oun ba baba oun sọrọ ko yee ṣe agbere, to si sọ nigba naa pe oun ṣetan lati ran an sọrun ti ko ba simi agbere ṣiṣe.

Nigba tawọn ọlọpaa gbe obinrin alaaganna yii de iwaju Onidaajọ Bamidele Ọmọtọṣọ, pẹlu ẹsun kan ṣoṣo to rọ mọ ipaniyan, wọn ni ẹsẹ to ṣẹ lodi sofin ipaniyan to jẹ ofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2012.

Lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ ṣinṣin, Agbefọba, Ọgbẹni Olowoyọ-Richard Ayọbami, pe ẹlẹrii marun-un, bakan naa lo mu iwe ti wọn fi gba ọrọ silẹ lẹnu obinrin yii pẹlu ọbẹ to fi gun ọkọ rẹ pa, aworan oku ọkunrin naa ati awọn ẹsibiti miiran.

Ninu awijare tiẹ, Agbẹjọro fun obinrin alaaganna yii, Ọgbẹni Emmanueli Adedeji, sọ pe iyaale ile naa ni arun ọpọlọ ni akoko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, o bẹ ile-ẹjọ lati tu onibaara oun silẹ ko le lọọ ṣe itọju aisan to n da a laamu.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Bamidele Ọmọtọṣọ sọ pe ki wọn gbe obinrin naa lọ saaye ọtọ lọgba ẹwọn, nibi ti wọn yoo ti ṣe ayẹwo fun un boya loootọ lo ni ọdẹ ori.

Leave a Reply