N’Ikirun, bireeki ọkọ akọyọyọ ja, lo ba gun ọlọkada lori 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin ọlọkada kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Mukaila Ọkẹdowo, lo pade iku ojiji rẹ lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lasiko ti bireeki ọkọ akọyọyọ kan ja niluu Ikirun, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Ọṣun.

Ohun ti a gbọ ni pe lati ọna Ọbaagun, loju ọna Ila si Ikirun, ni ọkọ naa ti n bọ, lasiko to si n da gẹrẹgẹrẹ ọna to kọja niwaju aafin Akinrun, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Bi dẹrẹba yii ti ri i pe bireeki ja lo ti n gbiyanju lati da mọto naa durọ, ṣugbọn gbogbo igbiyanju rẹ ko so eeso rere, gbogbo nnkan to wa loju ọna lo n mu gun titi to fi duro niwajuu geeti Akinrun.

Loju-ẹsẹ ni ọkunrin ọlọkada yii ku, ọpọlọpọ awọn ti wọn tun jọ wa nibẹ ni wọn fara pa yannayanna, bẹẹ ni ọpọ mọto ti wọn paaki soju ọna ko mori bọ ninu ijamba naa.

Alukoro ajọ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ọṣun, Kẹhinde Adeleke, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni okuta granite ni ọkọ akoyọyọ naa ko, nigba to si de inu Ọja-Ọba, niluu Ikirun ni bireeki rẹ ja.

Adeleke fi kun ọrọ rẹ pe pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọlọpaa atawọn ajọ ẹṣọ ojuupopo, wọn ti gbe oku ọlọkada naa lọ si mọṣuari, bẹẹ lawọn ti wọn fara pa ti wa nileewosan fun itọju.

Leave a Reply