Adewale Adeoye
Iku ni ere ẹṣẹ, eyi lo jọ pe o fa a ti adajọ ile-ẹj̀ọ kan lagbegbe Kubwa, niluu Abuja, fi paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun awọn ọrẹ meji kan, Yahuza Isah pẹlu Auwalu Mohammed, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn gbimọ-pọ lati ṣeku pa Mohammed Shaibu, lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn ji kẹkẹ Marwa rẹ lọ.
Agbefọba, Mayowa Adefioye, ṣalaye pe lọjọ keje, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2020, ni awọn eeyan naa dihamọra pẹlu nnkan ija oloro loriṣiiriṣii, ti wọn si da Shuaibu to n wa kẹkẹ Marwa rẹ lọna ni agbegbe Moore District, niluu Abuja, ni wọn ba fọ sipana mọ ọn lori titi to fi ku. Lẹyin ti wọn ri i pe ọkunrin naa ko le mira mọ ni wọn gbe kẹkẹ Marwa rẹ lọ. Ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ iwadii awọn agbofinro lori iṣẹlẹ naa, ọwọ pada tẹ awọn amookun-ṣika ẹda yii, ni wọn ba foju wọn ba kootu. Ẹsun ipaniyan ati lilo nnkan ija oloro lati digunjale ni wọn fi kan wọn.
Adefioye ni gbogbo iwadii to yẹ ki oun ṣe pata loun ṣe lati fidi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn eeyan naa mulẹ pe loootọ ni wọn mu wọn nitori pe wọn ṣeku pa Shuaibu ti ko ṣẹ wọn lẹnu iṣẹ oojọ rẹ. O ni ẹṣẹ ti wọn ṣe yii lodi sofin, ijiya nla si wa fun ẹni to ba ṣe iru ẹ labẹ ofin.
Adajọ ile-ẹjo giga naa to wa ni Kubwa, niluu Abuja, Abilekọ Asmau Akanbi Yusuf, sọ pe gbogbo ẹri ti agbefọba gbe wa siwaju oun yii fi han pe niṣe ni awọn ọdaran mejeeji yii mọ-ọn-mọ gbimọ-pọ lati ṣeku pa Shuaibu, wọn ko si ni awijare kankan lati sọ pe awọn kọ lawọn pa ọkunrin oni kẹkẹ Marwa ọhun lọjọ keje, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2020, ti wọn si tun ji kẹkẹ ẹ lọ ko too di pe ọwọ tẹ wọn.
O ni iku lo tọ si awọn eeyan naa labẹ ofin ifipa jale ati lilo ohun ija oloro lati ṣakọlu siiyan. Onidaajọ Mohammed ni ki wọn lọọ yẹgi fawọn mejeeji titi ẹmi yoo fi bọ lara wọn.