Monisọla Saka
Oku n sunkun oku, akaṣọleri n sunkun ara wọn lọrọ da fun ọmokunrin kan, Allison Obiajunwa, ti iyawo rẹ ku laipẹ yii, ti wọn si n mura lati ṣeto isinku rẹ, ṣugbọn lojiji ni ọkọ iyawo naa tun gan mọna nibi to ti n ṣiṣẹ ounjẹ oojọ rẹ, loku ba di meji fun mọlẹbi. Iyawo ku, ọkọ naa si tẹle e ni ko pẹ rara.
Titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn mọlẹbi ọmọkunrin naa to wa lati ipinlẹ Abia, ṣi n ṣọfọ iku gbigbona ti ọmọ wọn ọkunrin naa ku ni o ku ọjọ diẹ lati ṣe oku iyawo rẹ.
ALAROYE gbọ pe iṣẹ awọn to maa n tun ina ṣe ni ọmọkunrin to doloogbe yii n ṣe. Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn si pe e pe ko waa ba awọn paarọ waya kan nibi ẹrọ amunawa wọn. Lasiko to n paarọ waya tiransifọma naa lagbegbe kan nijọba ibilẹ Obingwa, nipinlẹ Abia, ni wọn lo gan mọna, ki awọn to wa nibẹ si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọmọkunrin naa ti sọda sodikeji aye.
Afi bii eedi lọrọ naa, nitori wọn ni Allinson ko wọ ibọwọ tabi ohun eelo tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna maa n wọ lati daabo bo ara wọn lasiko ti wọn ba fẹẹ yẹ iru nnkan bẹẹ wo.
Ọkan ninu awọn tọrọ naa ṣoju re to ba ileeṣẹ iroyin WithinNigeria sọrọ, sọ pe, “Nnkan to buru ju nibẹ ni pe iyawo ẹ to doloogbe yii ṣi wa nile igbokuu-pamọ-si, ti wọn si n ṣeto bi wọn yoo ṣe sinku ẹ laarin ọjọ perete ti wọn da sọna. Ọfọ nla gidi lo ṣẹ awọn mọlẹbi ọhun”.
Ọkunrin yii ni oun o tilẹ mọ ẹni ti eeyan iba di ẹbi ọrọ naa ru fun iwa aibikita ati iwa ọdaran to mu ẹmi eeyan lọ yii, boya ileeṣẹ mọnamọna ni abi oloogbe funra ẹ.