Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni ọwọ awọn ti tẹ meji ninu awọn afurasi to lọwọ ninu bi wọn ṣe lu ọmọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Ọlọrunfẹmi Tọpẹ, pa lẹyin to fi ọkọ ayọkẹlẹ Toyota rẹ kọ lu awọn ọlọkada kan, ninu eyi tawọn eeyan ku si.
Alukoro wọn, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, lo fidi eyi mulẹ fawọn oniroyin ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ taa wa yii.
Ọdunlami ni ko sẹni to ti i le sọ boya ọmọ Yahoo ni tabi bẹẹ kọ, nitori awọn eeyan ko fun awọn agbofinro laaye lati ṣe iwadii to yẹ lori iṣẹlẹ naa, ki wọn too ṣe idajọ lọwọ ara wọn.
O ni eeyan meji lo ku lójú-ẹsẹ ti ijamba ọkọ naa waye, ti awọn mẹfa si fara pa. Dipo tawọn to wa nibẹ iba si fi sare gbe awọn to fara pa lọ si ọsibitu, ọkunrin awakọ naa ni wọn fabọ le lori, ti wọn si lu u nilukulu titi to fi dakẹ mọ wọn lọwọ lẹyin ti wọn ti kọkọ dana sun ọkọ rẹ.
O fi kun un pe awọn obi awakọ naa ko si ninu ọkọ pẹlu rẹ lasiko ti iṣẹlẹ yii waye, o ni bi wọn ṣe gbọ nipa ohun to ṣẹlẹ ni wọn sare lọ síbẹẹ ṣugbọn tí awọn tinu n bi ọhun tun ya bo wọn, ki awọn ọlọpaa too ṣẹṣẹ fipa gba wọn silẹ lọwọ wọn.
Ọdunlami ni ọkan ninu awọn tọwọ tẹ naa jẹ oniṣẹ-ọwọ, nigba ti ẹnikeji rẹ n taja pẹẹpẹẹpẹ. O ni ẹni kan lara awọn mejeeji tọwọ tẹ lo ṣe agbatẹru bi wọn ṣe dana sun ọkọ oloogbe lẹyin to kọ lu awọn ọlọkada tan.
Ọdunlami ni awọn afurasi mejeeji ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ fun ẹsun ipaniyan, ko le jẹ ẹ̀kọ́ fun awọn to tun fẹẹ da iru rẹ laṣa.
O waa rọ awọn araalu ki wọn gba ẹmi ifẹ laaye laarin ara wọn, ki wọn si yago fun iwa ṣiṣe idajọ lọwọ ara wọn nigbakuugba ti iṣẹlẹ kan ba waye, eyi to bi wọn ninu.
Ọpọ awọn ta a fẹẹ fọrọ wa lẹnu wo ni wọn kọ lati ba akọroyin ALAROYE sọrọ nitori ibẹru, nigba ta a pada ṣabẹwo si agbegbe Ijọ-Mimọ, ni Ijọka, Akurẹ, nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Lẹyin-o-rẹyin ni ọkunrin kan to porukọ ara rẹ Tajudeen Ọlafisoye, ṣalaye fun wa pe oun wa nitosi nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye, bo tilẹ jẹ pe oun ko duro wo o tan ki oun too sa kuro nibẹ nitori ibẹru awọn agbofinro.
Tajudeen ni eeyan oun kan to n gbe ni Ijọka loun lọọ ki lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, tiṣẹlẹ naa waye, o ni b’oun ṣe ṣetan pẹlu ẹni ọhun ti oun n pada si agbegbe Oke-Aro, nibi ti oun n gbe, loun sadeedee gbọ gbaa, leyii to mu ki oun sare pada lati wo ohun to n ṣẹlẹ̀ gan-an.
O ni oun ri ọmọkunrin naa to sare jade ninu ọkọ rẹ lẹyin to ṣeesi fi ọkọ kọ lu ọlọkada kan ati ero to gbe sẹyin, lo ba n sa lọ nigba to ri i pe awọn eeyan kan n le oun.
O ni awọn to n le e ko wulẹ jẹ ko sọrọ lẹyin ti wọn ri i mu ti wọn fi bẹrẹ si i lu u pẹlu ọkan-o-jọkan ohun tọwọ wọn ba.
Tajudeen ni ohun ko le sọ boya wọn ri ohunkohun to jẹ mọ etutu ninu ọkọ rẹ, bẹẹ ni oun ko mọ boya ọmọ Yahoo ni loootọ tabi ko ri bẹẹ. O ni nigba toun ri i pe ọrọ naa ti fẹẹ maa la ti ẹmi lọ loju oun ko gba a mọ, ti oun si tete kuro nibi iṣẹlẹ naa nitori ibẹru.
Ẹnikan to tun ba wa sọrọ, ṣugbọn to kọ lati darukọ ara rẹ fun wa ni irọ ni wọn n pa nipa awọn nnkan etutu ti wọn n pariwo pe wọn ka mọ inu ọkọ rẹ
O ni ọpọ awọn eeyan agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni wọn mọ Tọpẹ bii ẹni mowo nitori ọkan ninu awọn gbajumọ ibẹ ni.
O ni ki i ṣe Ijọka lo n gbe, awọn obi rẹ ni wọn n gbe n’Ijọka. Ọkunrin yii ni oun gbọ pe ṣe ni wọn pe e lọjọ naa lati tete maa bọ lati waa ba awọn obi rẹ to n ba ara wọn ja nile wọn pari ija.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ ọdọ awọn obi rẹ yii lo n kanju lọ to fi ṣeesi fi ọkọ rẹ kọ lu ọlọkada kan.
Bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye lo ni o duro lati ṣe aajo awọn to kọ lu, ṣugbọn awọn janduku kan fẹẹ ṣuru bo o lati ṣe akọlu si i, o ni eyi lo ba a lẹru to fi sa wọ inu ọkọ rẹ pada lati sa asala fun ẹmí rẹ.
Ọkunrin to ba wa sọrọ ọhun ni ibi to ti n gbiyanju lati sa lọ lo tun ti ṣeesi lọọ kọ lu awọn mi-in.
O ni ahesọ patapata lawọn ọrọ ti wọn n sọ pe o jẹwọ ko too ku pe awọn mẹrindinlogun loun fẹẹ pa ki oun le lowo si i. O ni ṣe ẹni ti wọn ko gba laaye lati sọrọ rara ki wọn too pa a nipa ika ni yoo roju sọrọ ti wọn lo sọ?
Bakan naa lo ni ko si ẹri tabi aridaju kankan pe wọn ba ohunkohun to jẹ mọ nnkan etutu ninu ọkọ rẹ bii ero awọn eeyan kan ti wọn ni nítorí eyí ni wọn fi pa a.
Ijọba ipinlẹ Ondo naa ti sọrọ ta ko iṣẹlẹ ọhun ninu atẹjade kan ti Adele-Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, fi sita nipasẹ Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Abilekọ Bamidele Ademọla-Ọlatẹju lọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Ayedatiwa ni ki i ṣohun to tọna rara bi awọn eeyan ọhun ṣe ṣe idajọ lọwọ ara wọn lori awawi pe ẹni ti wọn pa naa n ṣe Yahoo.
O ni gbogbo awọn ti aje iwa ibajẹ ọrọ naa ba si mọ lori ko ni i lọ lai jiya, bẹẹ lo tun ba awọn to padanu eeyan wọn sinu iṣẹlẹ ọhun kẹdun.