Faith Adebọla, Eko
Niṣe lọrọ ba ibomi-in yọ fawọn onkọrin taka-sufee meji kan, Lawal Ajibawo, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, ati Sunday Akhigbe, ọmọ ọdun mejila pere, pẹlu bi wọn ṣe fẹsẹ ara wọn rin lọ sibi ti wọn ti fẹẹ kọrin sinu awo lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ṣugbọn to jẹ oku awọn mejeeji ni wọn gbe jade ninu ile orin ọhun laaarọ ọjọ keji, ọjọ Ẹti, Furaidee.
Coded Music Recording Studio to wa ni ibudokọ Awolusi, lagbegbe Alagbado, nipinlẹ Eko, niṣẹlẹ ọhun ti waye, ibẹ ni wọn ti lọọ kọrin sinu awo mọju, tawọn naa fẹẹ gbe awo orin jade.
Ki i ṣe awọn meji yii nikan ni nnkan ọhun ba, awọn mẹta mi-in ti wọn jọ wa ninu yara naa ati ẹni to n gba ohun wọn silẹ paapaa ṣi wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun bayii, tori digbadigba ni wọn sare gbe wọn lọ ṣọsibitu aladaani kan to wa nitosi, boya wọn le doola ẹmi wọn.
Gẹgẹ bi alaye ti Ọgbẹni Musiliu ṣe fun AKEDE AGBAYE, o ni itosi ile ikọrin naa loun n gbe, oun si ri awọn oloogbe mejeeji ọhun lalẹ Ọjọbọ ti wọn waa ṣe rẹkọọdu, ki wọn too wọle.
O ni ọpọ igba lo jẹ pe alẹ mọju lawọn to fẹẹ kọrin maa n wa sibẹ, boya nitori ariwo to maa n dinku loru, awọn onkọrin yii naa si ti maa n wa sibẹ daadaa.
Musiliu ni afi bo ṣe di owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, to yẹ ki wọn ti pa jẹnẹretọ ti wọn tan lalẹ, tori ina Nẹpa ti de nigba yẹn, ṣugbọn tawọn ṣakiyesi pe jẹnẹretọ naa ṣi n ṣiṣẹ, ṣugbọn ohun jẹnẹretọ nikan lawọn n gbọ, ko jọ pe eeyan wa ninu ile naa.
Eyi lo mu ki awọn kanlẹkun ibẹ, ṣugbọn ko sẹnikẹni to fesi. O ni pẹlu bawọn ṣe gba ilẹkun ọhun to, to ba tiẹ jẹ pe wọn gbagbe sun lọ ni, o yẹ ki ẹni kan taji ninu wọn, lawọn ọdọ kan laduugbo naa ba fipa jalẹkun.
O ni iyalẹnu ni lo jẹ pẹlu bawọn ṣe n wo gbogbo awọn mẹfẹẹfa ti kaluku wọn ti dubulẹ yakata kaakiri yara ọhun, awọn kan ṣi n pofolo, ti wọn n mi diẹdiẹ, ṣugbọn eemi naa ko delẹ mọ, niṣe lo da bi i ti atupa to ti fẹẹ ku, nigba tawọn oloogbe meji yii ti dakẹ ni tiwọn.
Nitori ofin, niṣe lẹnikan sare pe teṣan ọlọpaa Alagbado lori aago wọn, awọn si ni lati duro titi tawọn ọlọpaa fi de, ẹyin naa ni wọn too gbe awọn to ṣi n mi diẹdiẹ naa lọ sileewosan, awọn ọlọpaa ni wọn ko oku awọn oloogbe lọ si mọṣuari.
A gbọ pe nigba tawọn ọlọpaa ṣayẹwo yara naa, oriṣiiriṣii nnkan ni wọn ba bii egboogi oloro, amuku igbo, kọndọọmu ti wọn ti lo ati tuntun, ajẹku burẹdi ati igo ọti lile.
Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe afaimọ ni ko ma jẹ eefin jẹnẹretọ to ṣiṣẹ mọju naa lo ṣeku pa awọn oloogbe naa, to si ṣe awọn to ku leṣe, ṣugbọn awọn mi-in sọ pe oogun oloro tawọn eeyan naa mu le gbodi lara wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, SP Muyiwa Adejọbi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni Ọgbẹni Azeez Muritala ti wọn loun lo ni ibi ti wọn ti n kọrin naa ti wa lakata awọn ọlọpaa, wọn si ti gbe ọrọ naa lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni Panti, Yaba, fun iwadii to peye. O fi kun un pe awọn ṣi n duro de abajade ayẹwo awọn dokita.