Monisọla Saka
Ori lo ko awọn abilekọ meji ati ọmọ-ọwọ kan yọ lọwọ iku ojiji pẹlu bi tirela akẹru nla kan ṣe sọ ijanu rẹ nu, to si ya bara wọnu mọṣalaaṣi kan niluu Suleja, nipinlẹ Niger, lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii. Awọn eeyan mẹtẹẹta ti wọn ha sabẹ ọkọ naa nibi to lọọ fori sọ ni wọn ti ribi doola wọn lai jẹ pe ẹmi kankan ba iṣẹlẹ naa lọ.
Laago mẹfa aarọ kutukutu ọjọ Tusidee ọhun ni wọn ni iṣẹlẹ naa waye lagbegbe ọja nla kan ti wọn n pe ni Babangida Market, niluu Suleja.
Miliiki gbẹrẹfu ni wọn ni ọkọ akẹru yii ko, koto ati ibi kan to ri gbagungbagun ni dẹrẹba naa n gbiyanju lati yago fun loju titi to fi lọọ ṣubu sẹgbẹẹ kan apa ọwọ ẹyin mọṣalaṣi naa.
Ọkunrin kan tọrọ ọhun ṣoju ẹ, Abubakar Saleh, sọ pe, “Ko pẹ pupọ ti ọpọlọpọ awọn ẹlẹsin Musulumi fi mọṣalaṣi silẹ lọ sile koowa wọn lẹyin irun aarọ, ni nnkan bii aago mẹfa idaji niṣẹlẹ naa waye.
Apa ẹyin mọsalasi yẹn, nibi tawọn obinrin atawọn ọmọde maa n wa, ni tirela naa lọọ fori sọ.
Eeyan mẹta, to fi mọ ọmọ kekere kan, ni wọn ha si aarin awọn palapala ati erunrun idọti to wa nibẹ, eyi si jẹ ki wọn ṣeṣe gidi gan-an, loju ẹsẹ ni wọn si ti sare gbe wọn lọ sileewosan ijọba, iyẹn Suleja General Hospital, fun ayẹwo ati itọju ni kiakia”.
Nigba to n dupẹ lọwọ Ọlọrun, o ni Ọlọrun ba awọn ṣe e pe pupọ awọn eeyan ti kuro ni mọṣalaṣi lẹyin ti wọn kirun tan. O ni fọfọọfọ ni inu mọsalasi naa maa n kun lasiko irun, ṣugbọn Ọlọrun ṣeun pe awọn eeyan ti lọ sile wọn kiṣẹlẹ naa too waye, ti ko si mu ẹmi kankan dani.