Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa orile-ede yii ti le mẹta danu lara awọn oṣiṣẹ wọn kan ti wọn ṣiwa-hu lọjọ keje, oṣu yii, laarin ilu Kahutu, nipinlẹ Katsina.
Ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta naa ni pe wọn yinbọn ijọba to wa lọwọ wọn lai bikita rara, wọn fọn ọta ibọn to wa ninu ibon ọwọ wọn danu, leyii ti ko tọna, ati pe wọn tun ṣi agbara pẹlu ipo ti wọn ni lo lakooko ti wọn n ṣiṣẹ ilu lọwọ.
Awọn ọlọpaa ti kele ofin ọhun gba mu bayii ni: Insipẹkitọ Dahiru Shuaibu, Sagẹnti Abdullahi Badamasi pẹlu Sagẹnti Isah Danladi, ti wọn sọ pe ki wọn maa ṣọ gbajumọ olorin kan bayii nipinlẹ Kano lohun.
Alukoro ileeṣẹ awọn ọlọpaa lorile-ede yii, Ọmọọba Olumuyiwa Adejobi, lo sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin kan sọrọ niluu Abuja.
O ni o ṣe pataki fun ileeṣẹ ọlọpaa lati tete fi awọn oṣiṣẹ rẹ wọnyi jofin, kawọn araalu baa le nigbagbọ ninu awọn pe awọn ko ni i figba kan bọ ọkan ninu rara lori ẹni to ba ṣiwa-hu lawujọ wa.
Ọgbẹni Adejobi ni lẹyin ti fidio oniṣẹju diẹ (Video Clips) kan gba ori ayelujara kan, nibi tawọn ọlọpaa ọhun ti yinbọn soke lakooko ti wọn n tẹle gbajumọ olorin kan. Awọn araalu kan ti iwa awọn ọlọpaa naa ko tẹ lọrun si n kigbe kikan-kikan.
Ọgbẹni Adejọbi sọ pe ninu fidio ọhun lawọn ti ri awọn ọlọpaa mẹtẹẹta naa ti wọn n yinbọn ọwọ wọn danu, ti wọn ko si bikita rara pe owo nla ni ijọba apapọ n lo lati fi ra awọn ọta ibọn naa nigba gbogbo. Iwa ti ọn hu yii ni wọn sọ pe o lodi si ofin ileeṣẹ naa patapata.
O ni, ‘Lẹyin ta a yẹ fidio oniṣẹju diẹ kan bayii to gba ori afẹfẹ kan wo daadaa, nibẹ lati ri awọn ọlọpaa mẹtẹẹta yii, Insipẹkitọ Dahiru Shuaibu, Sagẹnti Abdullahi Badamasi pẹlu Sagẹnti Isah Danladi, ti ileeṣẹ ọlopaa ni ki wọn maa tẹlẹ gbajumọ akọrin kan nipinlẹ Kano fun aabo rẹ, ti wọn n yinbọn ọwọ wọn lai bikita rara pe owo nla ni awọn alaṣẹ ijọba ilẹ yii n lo lati fi ra awọn ọta ibon naa. Gbogbo ẹsun buruku ti a fi kan wọn patapata ni wọn jẹbi rẹ poo. Wọn jẹbi ẹsun pe wọn ṣibọn lo laarin ilu, wọn jẹbi ẹsun pe wọn fọn ọta ibọn ọwọ wọn danu lai nidii, wọn jẹbi ẹsun pe wọn ṣi agbara lo, ju gbogbo rẹ lọ, wọn tun jẹbi ẹsun pe lakooko ti wọn n yinbọn ọwo wọn yii, o le lọọ ba awọn ọmọde to wa lagbegbe naa tabi awọn to n lọọ jẹẹjẹ wọn. Fun idi eyi, ileeṣẹ ọlọpaa ni o ṣe pataki fun awọn lati le awọn ọlọpaa mẹtẹẹta naa danu kuro lẹnu iṣẹ ijọba ni kia.