Tẹgbọn-taburo lu ilẹ ẹgbọn wọn ta ni gbanjo l’Ekoo, nigba to fẹẹ bẹrẹ iṣe nibẹ lo ba ile lori ẹ

Adewale Adeoye

Ṣe ki i jẹ ti baba-tọmọ ko ma laala ni Yoruba maa n sọ, ṣugbọn owe yii ko ṣiṣẹ lọdọ awọn tẹgbọn-taburo kan, Obahor Paul, ẹni ogoji ọdun (40Yrs), ati aburo rẹ, Ọgbẹni Obahor Isaiah, ti wọn gbimọ pọ, ti wọn lo ayederu iwe aṣẹ, ti wọn si lọọ lu ilẹ ẹgbọn wọn ta ni gbanjo.

Lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ọdọ awọn ni tẹgbọn-taburo naa wa bayii, nibi ti wọn ti n ṣalaye idi ti wọn fi lẹdi apo pọ lati fi iwe awuruju kan ta ilẹ ọkan lara ẹgbọn wọn, Arabinrin Uzezi Obahor ni miliọnu mẹẹẹdọgbọn Naira (N25M) niluu Eko.

Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe ṣe lawọn tẹgbọn-taburo yii jọ gbimọ-pọ, ti wọn ṣe iwe awuruju kan lati fi sọ pe ẹgbọn awọn ti fun awọn ni aṣẹ ati agbara lati ta ilẹ naa to wa ni Abẹ́gẹ̀dẹ̀, nijọba ibilẹ Eti Ọsa, nipinlẹ Eko, lai jẹ ki ẹgbọn wọn to jẹ ojulowo ẹni to nilẹ ọhun mọ si i. Ṣugbọn aṣiri wọn pada tu, n lọlọpaa ba lọọ ko awọn mejeeji nile wọn to wa laduugbo Sọji Adepegba, lagbegbe Allen Avenue, niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.

Ohun to jẹ koro ọhun ya ọpọ awọn to gbọ lẹnu ni pe lati ọdun 2015 ni awọn tẹgbọn-taburo yii ti ta ilẹ ta a n sọrọ rẹ yii, ti wọn ko si jẹ ki ẹgbọn wọn mọ rara pe awọn ti ta ilẹ rẹ danu ni miliọnu mẹẹẹdọgbọn Naira.

Wahala nla bẹrẹ nigba ti Arabinrin Uzezi Obahor de ori ilẹ rẹ lati lọọ ṣe nnkan sori rẹ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun un pe awọn kan ti kọle nla sori ilẹ naa.

Nigba to foju rinju pẹlu awọn ti wọn ra ilẹ naa ni awọn yẹn ko ayederu iwe kan to fun awọn aburo obinrin yii laṣẹ ati agbara lati ta ilẹ ọhun lorukọ rẹ, wọn ni  awọn ẹbi rẹ yii lo forukọ rẹ ta ilẹ ọhun fawọn.

Arabinrin Uzezi Obahor ko fakoko ṣofo rara, ṣe lo gba teṣan ọlọpaa to wa lagbegbe naa lọ lati lọọ fọrọ ọhun to wọn leti, tawọn yẹn naa si tete lọọ fọwọ ofin mu gbogbo awọn ẹni tọrọ naa kan pata.

Nigba ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo ni wọn jẹwọ pe looọtọ awọn lawọn ta a pẹlu iwe awuruju fun ẹni to ra ilẹ naa, ati pe awọn ti na gbogbo owo tawọn gba nibẹ tan patapata.

Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ọhun ti ko wọn lọ sile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Ọgba, niluu Ikeja, fun ẹsun igbimọ-pọ lati jale ati hihuwa ọdaran nipa sisọ nnkan ẹlomi-in di tiwọn.

Nigba ti wọn n sọrọ niwaju adajọ, awọn mejeeji lawọn ko jẹbi pẹlu alaye, ki adajọ jọwọ, ṣiju aanu wo awọn.

Ọrọ ti awọn tẹgbọn-taburo yii sọ lo mu ki Agbefọba, Supọ Akeem Raji, ni ki adajọ sun ẹjọ naa siwaju, koun le raaye ṣewadii daadaa nipa iṣẹlẹ naa, niwọn igba ti awọn mejeeji ti ni awọn ko jẹbi. O ni oun ni lati ko awọn ẹri wa lati gbe ọrọ oun lẹsẹ pe awọn tẹgbọn-taburo ọhun jẹbi.

Onidaajọ B. O. Ọsunsanmi faaye beeli silẹ fawọn tẹgbọn-taburo yii pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) pẹlu oniduuro meji fun ẹnikọọkan.

Ṣugbọn o paṣẹ pe ki wọn ṣi lọọ ju wọn  sọgba ẹwọn Kirikiri, niluu Eko, titi digba ti awọn mejeeji yoo fi pese awọn ohun tile-ẹjọ naa beere lọwọ wọn.

Leave a Reply