Nnkan de! Awọn agbebọn ji oṣiṣẹ TRACE gbe

Faith Adebọla, Ogun

Ko ju bii iṣẹju diẹ ti Ọgbẹni Ọlaṣupọ Popoọla, ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ to n dari lilọ-bibọ ọkọ loju popo nipinlẹ Ogun, Traffic Compliance and Enforcement, tawọn eeyan mọ si TRACE, yoo bẹrẹ iṣẹ ọjọ naa lawọn afurasi agbebọn kan tẹnikan o mọ ibi ti wọn ti wa rẹbuu rẹ lọna, wọn si ji i gbe wọgbo.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye ni nnkan bii aago mẹfa aabọ owurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, laarin agbegbe kan ti wọn n pe ni Fidiwọ, si Eledumare, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, eyi to wa lọna marosẹ Eko si Ibadan, niṣẹlẹ naa ti waye.

Ohun ta a gbọ ni pe niṣe l’Ọlaṣupọ ati ẹlẹgbẹ rẹ kan jọ n lọ sibi ti wọn yan wọn si lati maa dari ọkọ laaarọ ọjọ naa, afi bawọn agbebọn naa ṣe yọ si wọn lojiji latinu igbo to wa lẹgbẹẹ ọna, ti wọn si ji ọkan ninu wọn gbe. Ori ko ẹni keji yọ latari bi wọn ṣe lo sare, gigisẹ rẹ si fẹrẹ le maa kan an nipakọ.

Ẹnikan to ba ALAROYE sọrọ lori aago, amọ ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe latigba tiṣẹlẹ naa ti waye lawọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ alaabo fijilante ti bẹrẹ si i tọpasẹ awọn ajinigbe naa.

Ẹni naa tun sọ pe awọn alaṣẹ TRACE ko fẹẹ pariwo iṣẹlẹ yii sita, o ni eyi ni ko jẹ kawo ọrọ naa tete lu lẹsẹkẹsẹ.

ALAROYE gbiyanju lati ba Alukoro ajọ TRACE sọrọ, amọ ko gbe aago ẹ ta a pe leralera, bẹẹ ni ko ti i fesi satẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ si i titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ.

Amọ ṣa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni, “Loootọ niṣẹlẹ naa waye, awọn ẹni ẹlẹni yii n lọ sẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ wọn lawọn janduku kan ti wọn ti lugọ de wọn ninu igbo yọ si wọn lojiji, ti wọn si ji ẹnikan gbe. Awọn ọlọpaa atawọn fijilante, awọn ọlọdẹ agbegbe naa ti n tọpasẹ wọn. Bẹẹ lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n mojuto iwa ijinigbe ti n ṣiṣẹ lori ẹ. Mo fi da a yin loju pe gbogbo awọn olubi naa lọwọ wa maa tẹ, ta a si maa fi wọn jofin”.

O fikun un pe: “Ipinlẹ Ogun ki i ṣe ibi tawọn ọdaran yoo sọ di ibuba wọn. Ninu ki wọn kọri sibomi-in, ki wọn kuro nipinlẹ yii, tabi ka fin wọn jade bii okete, lati fimu wọn kata ofin, wọn gbọdọ ṣe ọkan nibẹ.” Gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply