Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oju bọrọ ko ṣee gbọmọ lọwọ ekurọ lọrọ naa da fun awọn agbofinro lasiko ti wọn fẹẹ gba tọkọ-taya kan ti aọn agbebọn naa ji gbe silẹ lọwọ wọn.
Niṣe ni iro ibọn n pera wọn ranṣẹ, awọn ajinigbe yii lawọn ko ni i fẹ, awọn ọlọpaa naa laọn ko ni i gba. Lasiko ti wọn n dan agbar wo yii ni ibọn ba ọkan ninu awọn ajinigbe naa, to si ku fin-in-fin-in
Tẹ o ba gbagbe, ALAROYE ti gbe iroyin tọkọ-tiyawo kan, Ọgbẹni Jonah ati iyawo rẹ, ti wọn n bọ lati iṣọ-oru laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ti awọn eeyan naa ji gbe nipinlẹ Ọṣun.
Ṣọọṣi la gbọ pe awọn eeyan naa ti n bọ ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ naa. Bi wọn ṣe de agbegbe Kelebe, loju ọna Iragbiji si Oṣogbo, ni wọn kan igi nla kan ti awọn agbebọn naa gbe di oju ọna. Ṣugbọn awọn eeyan naa ko mọ pe awọn oniṣẹ ibi naa lo gbe igi ọhun dina.
Lasiko ti wọn rọra n rin nitori igi to wa ni oju ọna naa pẹlu ọkada wọn lawọn agbebọn naa jade, ti wọn si ko awọn mejeeji wọnu igbo lọ.
Alaroye gbọ pe awọn agbebọn naa ti beere miliọnu lọna ọgbọn Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ awọn tọkọ-tiyawo naa.
Owo itusilẹ yii lawọn agbebọn ọhun fẹẹ lọọ gba lale ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti awọn ọlọpaa ti wọn ti fara pamọ sagbegbe fi ko wọn loju, ti wọn si wọya ija pẹlu wọn.
Ọlọpaa pa ọkan lara wọn, nigba ti awọn yooku sa lọ pẹlu ọta ibọn lara wọn, ṣugbọn wọn ko ri owo ti wọn fẹẹ waa gba ọhun gba.
Asiko yii lawọn tọkọ-tiyawo naa sa jade lahaamọ wọn, ọtọọtọ si nibi ti onikaluku sa gba. Ṣugbọn awọn agbofinro ti ri aọn mejeeji, wọn si ti da wọn pada sọdọ awọn mọlẹbi wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe iṣẹ awọn ko ti i pari lori ọrọ naaa nitori awọn fẹẹ mu awọn agbebọn ti wọn sa lọ pẹlu ọta ibọn lara wọn ọhun.
O ke si awọn araalu lati ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii naa lati le fopin si iwa ibajẹ lawujọ wa.