Nitori ẹsun ole, baba yii febi pa awọn ọmọ ẹ titi ti meji fi ku ninu wọn

Faith Adebọla, Ogun

Okun to gbe aparo baale ile ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Gbenga Ogunfadekẹ yii, ki i ṣe pampẹ kekere rara, afaimọ ni ọkunrin naa ko ti ran ara ẹ lẹwọn fọpa wọn, iyẹn bọrọ ẹ ko ba ja si iku, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o so awọn ọmọ ẹ mẹtẹẹta mọlẹ bii ẹran sinu yara kan, o ti wọn mọle, ko jẹ ki wọn rita fun ọpọlọpọ ọjọ, o lawọn ọmọ naa n jale, bẹẹ lo febi pa wọn mọ ibi to ti wọn mọ titi tawọn meji fi ku ninu awọn ọmọ naa, lo ba lọọ sin oku wọn ni oku oru.

Agbegbe kan nijọba ibilẹ Ibiade/Waterside, nipinlẹ Ogun, lọwọ  ẹṣọ Amọtẹkun ti tẹ afurasi ọdaran yii, to fi dero ahamọ wọn, nibi to ti n jẹwọ ẹṣẹ ẹ fawọn to n ṣewaadi.

Alaye ti Kọmandanti ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, Alagba David Akinrẹmi, ṣe ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’Alaroye nipa iṣẹlẹ ọhun ni pe ọmọ mẹta ni iyawo akọfẹ afurasi yii, Busọla Otuṣẹgun, loun bi fun ọkọ rẹ, ko too di pe ina ko wọ mọ laarin wọn mọ, to fi ko jade lọọdẹ rẹ. Ilu Warri, nipinlẹ Delta, lọkọ mi-in tobinrin naa fẹ wa, ibẹ lo si wa titi di ba a ṣe n sọ yii.

Obinrin yii ṣalaye pe ọjọ-ori awọn ọmọ toun fi silẹ fun baba wọn yii je ọmọọdun mejidinlogun, ekeji jẹ ọmọọdun mẹtadinlogun, nigba ti abikẹyin jẹ ọmọọdun mẹẹẹdogun.

Obinrin to mẹjọ ọkọ aarọ ẹ lọ si tọlọpaa ọhun ṣalaye pe latigba toun ti kuro lọdọ afurasi yii, ko sigba toun o ki i pe e lori aago lati beere alaafia awọn ọmọ oun, to si maa n sọ foun pe daadaa ni gbogbo wọn wa, tori ko foun lanfaani lati ba awọn ọmọ naa sọrọ funra oun, oun o si ba a ṣe wahala kan nipa ẹ.

O ni lọgbọnjọ, oṣu Kẹta, to kọja yii, eyi abikẹyin awọn ọmọ naa lọ sọdọ aunti oun kan ti wọn jọ wa nijọba ibilẹ Ibiade, ẹsẹ lo lọmọ ọhun fi rin lọ, niṣe lo yọ jade lati lọọ fẹjọ ohun to ṣẹlẹ sawọn sun mọlẹbi iya rẹ ọhun.

Wọn ni tẹkun-tomije lọmọ ọhun fi ṣofofo fun aunti oun pe baba awọn ti pa awọn ẹgbọn oun meji, o loun nikan loun ṣẹku si i lọdọ, o ni niṣe ni baba naa so awọn mẹtẹẹta mọlẹ bii ẹran, o ti awọn mọnu yara kan, latari ẹsun ole jija to fi kan awọn.

Ọmọ ọhun ni ọpọlọpọ ọjọ ni baba yii ko fi fun awọn lomi debi ti yoo fun awọn lounjẹ, laarin oṣu Kẹrin si Ikẹfa, ọdun to kọja, tiṣẹlẹ aburu naa waye.

O ni latinu ahamọ ti baba awọn ti awọn mọ ọhun ni aarẹ ti mu awọn ẹgbọn oun mejeeji, Yusuf Ogunfadekẹ ati Dasọla Ogunfadekẹ, ti wọn si ku, n ni baba naa ba lọọ sinku wọn sinu igbo tẹnikan o mọ, asiko yii loun raaye sa jade.

Ọrọ yii ni wọn fi to iya awọn ọmọ naa leti, lo ba mẹjọ ọkọ atijọ naa waa fi sun awọn Amọtẹkun, wọn si tẹle e lọ sọdọ baba ti wọn n sọ yii, wọn fi pampẹ ofin gbe e.

Akinrẹmi ni awọn ṣewadii, lati fidi ootọ mulẹ, wọn lọkunrin naa jẹwọ pe ni tododo, oun ti awọn ọmọ oun mẹtẹẹta mọle fun ọjọ diẹ, o nidii toun fi ṣe bẹẹ ni lati kọ wọn lọgbọn lile tori niṣe lawọn ọmọ naa n ba oun loju jẹ kiri igboro pẹlu bi wọn ṣe n jale, ti okiki iwa buruku wọn si n kan kaakiri.

O loun ko febi pa wọn, amọ ko pẹ toun tu wọn silẹ ni aisan kan ta le meji ninu wọn, amọ ko sowo lọwọ oun toun le fi tọju wọn, n lawọn mejeeji ba ku mọ oun loju laarin ọsẹ diẹ si ara wọn, oun si sin wọn.

O tun sọ fawọn Amọtẹkun pe oun gbe ọkan ninu awọn ọmọ to ku ọhun de ileewosan, amọ nigba ti wọn ni ko darukọ ọsibitu to gbe wọn lọ, ati adirẹsi rẹ, kabakaba lo n wi.

Wọn tun ni ko mu awọn de oju oroori ibi to loun si awọn ọmọ ẹ ọhun si, o si mu wọn lọ loootọ, wọn fun jagunlabi yii ni ṣọbiri lati hu oku awọn ọmọ ọhun jade, wọn lo gbẹlẹ gbẹle titi, wọn o ri ohun to jọ oku, ko tiẹ si apa pe wọn ti sinku kan sawọn ibi mejeeji to mu wọn lọ.

Lẹyin eyi ni wọn tu ile afurasi yii kanlẹ, wọn si ri awọn oogun abẹnugọngọ to ko jọ, o jẹwọ pe iṣẹ babalawo loun n ṣe, amọ awọn Amọtẹkun ni afaimọ ni ki i ṣe ọkan lara awọn afeeyan-ṣetutu ni.

Ohun mi-in ti wọn lo tun mu kọrọ ọkunrin yii gba ifura ni pe ni gbogbo asiko ti iṣẹlẹ yii fi waye, ko fọrọ naa to ẹda Ọlọrun kan leti, niṣe lo ṣe gbogbo ẹ ni oku oru, koda ko jẹ kawọn mọlẹbi ẹ ati tiya ọmọ naa mọ si i pẹlu.

Ṣa, wọn ti lawọn maa taari afurasi yii sọdọ awọn ọlọpaa, ki wọn le tubọ ṣewadii nipa ẹ, ati lori iṣẹlẹ iku abaadi to pa awọn ọmọ rẹ mejeeji ọhun, ki wọn le foju ẹ bale-ẹjọ nibaamu pẹlu ofin.

Leave a Reply