Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Samad, to n wa Maruwa, ti dero ọrun bayii. Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn pa a siwaju mọṣalasi Abayawo, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara. Lẹyin ti wọn yinbọn pa a tan ni wọn tun yọ oju ẹgbẹ osi rẹ, ti wọn si tun ge ọwọ ẹgbẹ osi rẹ lọ lasiko ti awọn eeyan naa fija pẹẹta lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii.
Ni nnkan bii aago mejila oru ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wahala naa bẹrẹ, ti awọn olugbe agbegbe Abayawo, titi de Gambari, ko si le foju le oorun. Ija agba la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n ja, ti wọn si n rọjo ibọn funra wọn bii ẹni pe omi n da lati oju ọrun.
Ẹnikan to n gbe agbegbe Abayawo, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ni awọn deede ri awọn gende-kunrin ti wọn pọ, ti wọn gbe kẹkẹ Maruwa kalẹ, ti gbogbo wọn si ko ibọn lọwọ.
O tẹsiwaju pe nigba to to isẹju diẹ ni gbogbo adugbo daru, ti wọn si n yinbọn leralera, ti onikaluku si n sa kijo-kijo fun ẹmi rẹ. O fi kun un pe lati aago mẹsan-an alẹ ti ija naa ti bẹrẹ, aago mẹrin idaji ti Samad jade sita lo ko sọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii, ti wọn si yinbọn pa a.
Ọna kọrọ ti Samad sa lọ ni wọn le e lọ, ti wọn fi yinbọn mọ ọn, lẹyin ti wọn ri i pe o ti ku ni wọn wọ oku ẹ si oju titi, niwaju mọsalasi, ti wọn si yọ oju osi ati ọwọ osi rẹ lọ.
Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, ni wọn lọọ sinku Samad si itẹkuu Musulumi to wa lagbegbe Òṣeré, niluu Ilọrin.