Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn alaṣẹ ijọba orileede yii ti sọ pe awọn ti dawọ eto ikanniyan ti wọn sọ pe yoo bẹrẹ laarin ọjọ kẹta sọjọ keje, oṣu Karun-un, ọdun 2023 duro, titi digba ti ijọba tuntun to n bọ lode laipẹ maa fi sọ pe akoko bayii loun fẹẹ ṣe e.
Minisita fun eto iroyin lorileede yii, Alhaji Lai Mohammed, lo sọrọ eleyii di mimọ fawọn oniroyin niluu Abuja, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, lẹyin ipade pataki kan to waye laarin Aarẹ Buhari atawọn igbimọ iṣejọba rẹ.
Minisita naa sọ pe, ‘‘Aarẹ orileede yii, Mohammadu Buhari ti faṣẹ si i pe ki wọn dawọ eto ikanniyan ti wọn fẹẹ ṣe laarin ọjọ kẹta sọjọ keje, oṣu Karun-un, ọdun 2023, duro digba tijọba tuntun to n bọ lọna maa fọwọ si. Bo tilẹ je pe wọn ti dawọ rẹ duro, a mọ ipa pataki ti eto ikanniyan naa maa ko ninu eto idagbasoke ọrọ aje ilẹ wa.
‘‘Ọdun kẹtadinlogun ree ta a ti ṣeto ikaniyan gbẹyin nilẹ wa, eyi ko daa to rara fun orileede to tobi daadaa bii Naijira.
‘‘Awọn alaṣẹ gboriyin fun ajọ eleto ikanniyan fun iṣẹ takun-takun ti wọn ti ṣe ni ipalẹmọ fun eto naa. Gbogbo iṣẹ ti wọn ti ṣe yii ni yoo jẹ ki eto naa waye pẹlu irorun lasiko ti wọn ba fẹẹ ṣe e. Aarẹ Buhari ti ni kajọ eleto ikanniyan ilẹ wa maa ba awọn akọ iṣẹ kọọkan ti wọn n ṣe lọ nipa eto naa.