Mọto mọkanla atawọn nnkan olowo nla mi-in ni wọn ba lọwọ ọmọ Yahoo tọwọ tẹ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa magomago ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, (EFCC) ti tẹ ayederu ọlọpaa kan, Tijani Idris, pẹlu awọn afurasi ọmọ Yahoo mejilelogoji (42) ti wọn n lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara.

Idris, to n gbe niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, to n pera ẹ lagbofinro yii l’ALAROYE gbọ pe o ti fi orukọ iṣẹ ọlọpaa lu awọn eeyan ni jibiti nigboro ilu naa, ṣugbọn ọwọ awọn ojúlówó agbofinro tẹ ẹ niluu Ẹdẹ, lọjọ Ẹtì, Furaidee, ọjọ karùn-ún, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Lọjọ Jimọ yii kan naa lọwọ awọn EFCC tẹ awọn afurasi onijibiti ti wọn n pe lọmọ Yahoo mejilelogoji, niluu Ijẹbu-Ode.

Awọn ohun ti wọn ri gba lọwọ ọkan ni awọn afurasi ọdaran naa ni ọkọ ayọkẹlẹ mọkanla; oniruuru ẹrọ kọmputa agbeletan; ọpọlọpọ ẹrọ ibanisọrọ iPhone; aago ọrun ọwọ apple; awọn ẹrọ iṣere alaworan (video games) ati eyin goolu ti apa miliọnu Naira kekere ko ka.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, Alukoro fun ajọ EFCC nilẹ yii, Ọgbẹni Wilson Uwujaren, sọ pe ajọ naa ti n ṣeto lọwọ lati foju awọn afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ ni kete ti awọn ba pari iwadii gbogbo lori ẹsun jibiti ti awọn fi kan awọn mẹtẹẹtalelogoji (43) yii.

 

Leave a Reply