Ọlawale Ajao, Ibadan
O kere tan, mẹfa ninu awọn olukọ ileewe girama to jẹ tijọba ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti padanu ipo wọn lẹnu iṣẹ.
ALAROYE gbọ pe nitori bi wọn ṣe ba awọn akẹkọọ lọwọ ninu magomago idanwo nijọba ṣe fiya naa jẹ wọn.
Ninu lẹta kan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ kọ ranṣẹ sawọn olukọ tọrọ ọhun kan ni wọn ti kede ijiya naa lopin ọsẹ to kọja yii.
Ọgbẹni Orowale M.I. ti i ṣe Akọwe ajọ TESCOM, iyẹn ajọ to n ṣakoso iṣẹ olukọ nipinlẹ Ọyọ lo kọ lẹta naa jade.
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu lẹta ọhun, awọn olukọ ti wọn gba ipo lọwọ wọn wọnyi ni wọn fi aṣiri idanwo han awọn akẹkọọ kan ninu idanwo Wayẹẹki (WASCE) ti wọn ṣe kọja, eyi to lodi si ofin eto ẹkọ nibi gbogbo kaakiri agbaye.
Gbogbo awọn olukọ to lọwọ ninu iwa buruku yii nijọba ti ja irawọ wọn, ti wọn si ti gbe wọn kuro lati ipo giga ti wọn wa pada si ipo kekere ti wọn ti fi silẹ lati ọdun bii meloo kan sẹyin.
Ileewe kan ti wọn n pe ni Progressive Secondary Grammar School, niluu Tede, ni mẹrin ninu awọn olukọ mẹfẹẹfa ti n ṣiṣẹ.
Orukọ mẹrẹẹrin ti wọn ṣe bẹẹ fiya jẹ ni Abilekọ Mustapha Bọlanle Nureni, ẹni ti wọn da pada sori akaba kẹrinla latori akaba kẹẹẹdogun to wa tẹlẹ;
Ahmed Adamu Ademọla (lati akaba kẹwaa si ikẹsan-an); Titilọla Ajelẹyẹ John (akaba kẹwaa si ikẹsan-an ati Adegbọla Abraham Titilọpẹ, ẹni to wa lori akaba kẹjọ tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn da pada sori akaba keje bayii.
Ileewe girama kan ti wọn n pe ni Ọwọ Community Grammar School, to wa niluu Ọwọ, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ, lawọn olukọ meji yooku ti n kọ awọn akẹkọọ. Orukọ wọn ni Ogunkunle Musibau O. Ati Popoọla Akeem Abiọla.
Ọgbẹni Popoọla ni wọn gbe kuro lori akaba kẹjọ, ti wọn si da a pada sori akaba keje ninu akaṣọ agbega ipo lẹnu iṣẹ ijọba, nigba ti wọn da Ọgbẹni Ogunkunle pada sori akasọ kẹtala lati ori akaṣọ kẹrinla to wa tẹlẹ.
“Lẹyin ti iwadii ti fidi ẹ mulẹ pe awọn olukọ wọnyi lọwọ ninu magomago idanwo girama (WASCE) ọdun 2022 ti wọn ṣe kọja yii, ajọ to n ṣeto idanwo yii (WAEC), ti pinnu lati da awọn olukọ to huwa ẹṣẹ yii pada sẹyin pẹlu igbesẹ kọọkan lori akaba ipo wọn lẹnu iṣẹ”, bẹẹ lajọ WAEC ṣe kọ ọ ninu lẹta kan ti wọn kọ si ọga agba awọn olukọ lagbegbe ti wọn ti huwa ọdaran naa.