Ọlọpaa gba eeyan mejilelogun silẹ lọwọ ajinigbe

Faith Adebọla

Iku ti iba pa ni, bo ba ṣi ni ni fila, o yẹ ka dupẹ ni. Ọrọ yii lo wọ bi idunnu ati ọpẹ ṣe gbẹnu awọn mọlẹbi awọn eeyan mejilelogun kan tileeṣẹ ọlọpaa olu-ilu ilẹ wa l’Abuja, ṣẹṣẹ doola ẹmi wọn lakoolo awọn ajinigbe ti wọn ti mu wọn nigbekun lati bii oṣu kan sẹyin, wọn ti ri wọn gba jade, ni wọn ba n dupẹ lọwọ Ọlọrun.

Kọmiṣanna ọlọpaa Abuja, CP Haruna Garba, lo fọrọ yii lede ninu ipade kan to ṣe pẹlu awọn oniroyin lolu-ileeṣẹ wọn lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ta a wa yii.

O lawọn lọọ ṣe ọpureṣan akanṣe kan lọjọ kẹta, oṣu Karun-un yii, nibi tawọn ti fi ọgbọn-inu ṣakọlu sawọn ibuba ti awọn ajinigbe agbebọn ẹda naa ko awọn ẹni ẹlẹni ti wọn ji gbe pamọ si ninu igbo kijikiji kan, Ọlọrun ba awọn ja ija ọhun, ko sẹni to ku ninu awọn ọlọpaa ti wọn kopa, bẹẹ lọta ibọn ko ba eyikeyii lara awọn ti wọn wa londe ọhun. Eeyan mejilelogun lo lawọn ri gba pada, ti wọn dominira lọwọ awọn ajinigbe naa, bo tilẹ jẹ niṣe lawọn to ji wọn gbe fẹsẹ fẹ ẹ nigba tawọn gbeja ko wọn loju.

Baalẹ ọkọ ilu, olori abule Chida, to wa ni kansu Kwali, l’Abuja, wa lara awọn ti wọn da nide ọhun, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn ji oun atawọn ara abule rẹ gbe.

Kọmiṣanna ọlọpaa naa kede pe: “Ikọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti iwa ijinigbe ṣiṣẹ takun-takun laipẹ yii lagbegbe ati ayika ẹnu aala ipinlẹ Kogi si Nasarawa ati Abuja, a si ti gba awọn eeyan mẹrinla silẹ lakata awọn ajinigbe, baalẹ abule Chida wa ninu wọn.

“Mẹwaa lara awọn ta a ri tu silẹ yii ni aisan oriṣiiriṣii ti mu, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe aisan to lagbara ju. Oju-ẹsẹ la ti ko wọn lọ sọsibitu, wọn ti gba itọju, a si ti fa wọn le awọn mọlẹbi wọn lọwọ.

“Bakan naa lawọn agbegbe ti mo mẹnuba loke yii, a tun ri eeyan mẹjọ mi-in gba jade ninu ahamọ awọn ajinigbe kan laipẹ yii. Orukọ wọn ni Buba Galadima, Sarki Galadima, Audu Galadima, Musa Buba, Mohammed Isa, Hassan Audu, Aminu Ahmadu ati Abubakar Mallam. Ọjọ kẹtala, oṣu to kọja, iyẹn oṣu Kẹrin, ni wọn ji wọn gbe labule Lapai ati Tunda, nipinlẹ Niger. A ti ko wọn lọ sọsibitu fun ayẹwo ati itọju.”

Ọkunrin naa waa fawọn araalu lọkan balẹ, o ni lori ọrọ awọn ajinigbe yii, arọni o wale, Onikoyi o sinmi ogun ni o, o lawọn maa tẹsiwaju lati fẹ ata ija si wọn loju ni titi ti wọn fi maa jawọ iwa laabi wọn, tabi ki wọn wabigba.

Leave a Reply