Gomina Makinde ko gbọdọ ti i fi ẹnikẹni jẹ Alaafin lasiko yii-Idile ọmọọba Ọyọ 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn idile ọba Alaafin Ọyọ mẹsan-an ti rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lati ma ṣe yan ẹnikẹni sori apere ọba ilu naa, afi nigba ti ọrọ ẹjọ to n lọ lọwọ ni kootu lori ọrọ oye ọba naa ba pari.

Awọn idile oye wọnyi ni wọn jẹ arọmọdọmọ fun

mẹsẹẹsan ninu awọn ọmọkunrin Alaafin Atiba to tẹ ilu Ọyọ tuntun do, ti awọn naa jẹ ninu ogun Alaafin Atiba, ṣugbọn to jẹ pe awọn ko ti i gori itẹ baba wọn ri ni tiwọn, to jẹ awọn ọmọ idile Alowolodu ati Agunloye nikan ni wọn n jọba ninu idile oye mọkọọkanla.

Orukọ awọn idile mẹsẹẹsan ọhun ni Adelabu, Adediran Ẹsẹ Apata, Ọlanitẹ, Adeṣiyan, Adeṣọkan Baba Idọdẹ, Itẹade Abidẹkun, Adeitan, Tẹlla Okitipapa ati Tẹlla Agbojulogun.

Latigba ti ori itẹ ọba ti ṣofo niluu Ọyọ latari ipapoda Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, ti i ṣe Alaafin karundinlaaadọta (45th) ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni gbogbo idile Atiba, atawọn mejeeji ti wọn ti jọba lọpọlọpọ igba ri, atawọn mẹsẹẹsa-an  ti wọn ko ti i jẹ ẹ ri ti jọ n dupo Alaafin, ṣugbọn ti awọn Ọyọmesi (awọn Afọbajẹ) ko ti i ri ẹnikankan ninu wọn fa kalẹ lati gori itẹ ọba.

Awọn idile Alaafin Ọyọ ti ko ti i jọba ilu naa ri ti waa woye pe ko ni i daa ko jẹ pe ninu idile mejeeji to ti maa n da ọba jẹ tẹlẹ naa ni wọn yoo tun ti mu ọba tuntun lọtẹ yii.

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn idile mẹsẹẹsan-an, Ọmọọba Afọlabi Adeṣina, lati idile Adeitan, fi aidunnu wọn han si igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ n gbe lori ọrọ eto lati fi ọba tuntun jẹ lode Ọyọ.

Ọmọọba Adeṣina, ẹni to dupẹ lọwọ Gomina Makinde fun bo ṣe mu iṣejọba rere lọkun-un-kundun nipinlẹ yii tun waa fi asiko yii rọ ijọba lati mu igbaye-gbadun araalu lọkun-un-kundun, ki gomina naa si maa tẹlẹ ofin ninu ohun gbogbo to ba n ṣe.

Gẹgẹ bí ṣe sọ, “A rọ Gomina Makinde lati bọwọ fun ofin lori ipo Alaafin, ko ma ṣe fi ẹnikẹni jọba, afi lẹyin ti ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ oye ọba Ọyọ maa fi pari”

“Ko ni i bojumu rara ki ijọba kanju fi ọba sori itẹ l’Ọyọọ bayii, ohun to ti daa ju ni pe ki gomina ri i daju pe gbogbo awuyewuye ati ẹjọ to wa lori ipo Alaafin yanju tan pata ko too gbe igbesẹ lati yan ọba tuntun. Eyi nikan lọna ti wọn le gba fi Alaafin tuntun jọba pẹlu akoyawọ.

Ninu Ipade oniroyin kan ṣaaju l’Ọmọọba (Alhaji) Hammed Isiaka to n dupo Alaafin lorukọ idile Adelabu ti rọ awọn Ọyọmesi lati ṣatunṣe si ọrọ ọba jijẹ l’Ọyọọ lọna ti gbogbo idile to jẹ arọmọdọmọ Alaafin Atiba naa yoo fi lanfaani lati maa gori itẹ baba nla wọn.

Leave a Reply