Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹẹmeji ni mo ti ba wọn kopa ninu ijinigbe, a ko ti i r’owo gba teni ta a ji fi ku sọdọ wa-Akinyẹmi
Eyi atawọn ọrọ mi-in lo n jade lẹnu ọmọkunrin ajinigbe kan, Akinmọla Oyekanmi, lasiko tawọn oniroyin n fọrọ wa a lẹnu wo lolu ileeṣẹ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo, eyi to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun ọhun ni iṣẹ agbẹ loun n ṣe tẹlẹ ki kadara too sun oun lọ sidii iṣẹ ajinigbe. O lawọn mẹta lawọn jọ n ṣiṣẹ pọ ki ọwọ too tẹ oun nìkan, ti awọn ẹlẹgbẹ oun meji yooku si raaye sa lọ ni tiwọn.
Oyekanmi ni ẹẹmeji loun ti ba wọn lọ soko ijinigbe, toun sí r’owo gba níbẹ dáadáa. O ni ẹlẹẹkẹta tawọn jọ ṣe ni ti ọkunrin kan tawọn ji gbe lagbegbe Mowe, nipinlẹ Ogun, laipẹ yii. Awọn ẹbi ọkunrin naa ko ti i sanwo itusilẹ titi to fi ku sinu igbekun awọn latari ìbọn to ṣeesi ba a latọwọ oun.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Adari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni ọwọ awọn tẹ Oyekanmi pẹlu ifọwọsowọpọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ogun.
O ni awọn ti ṣawari ẹbi ọkunrin ti wọn pa naa, ati pe laipẹ lawọn yoo fi afurasi tọwọ tẹ yii ṣọwọ si wọn nipinlẹ Ogun, nibi tiṣẹlẹ ọhun ti waye fun igbesẹ to yẹ.