Mo ti dariji gbogbo awọn to ṣẹ mi-Adeleke

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, ti sọ pe oun ti fi tọkantọkan dariji gbogbo awọn to da bii ẹni pe wọn ṣe oun lọna kan tabi omi-in ninu irinajo oun si ipo gomina.

Lasiko ti Adeleke ṣabẹwo, ‘ẹ ṣẹun’ si aafin Ataọja ti ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Ọlaonipẹkun ati Timi Ẹdẹ, Ọba Munitudeen Adeṣọla Lawal, Laminisa 1, lẹyin idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii lo sọrọ naa.

Gomina ṣalaye pe, “Mo ti di gomina fun gbogbo eeyan. Fun awọn ti ko dibo fun mi, mi o ni ohunkohun ninu si wọn, bi ọrọ ijọba tiwa-n-tiwa ṣe ri niyẹn. Mo ti dariji gbogbo awọn ti wọn ṣe mi lasiko ti mo n lakaka lati sin awọn eeyan mi.

“Bo tilẹ jẹ pe awọn kan dide ọtẹ si igbesẹ wa, gbogbo rẹ ti di afisẹyin bayii. Ohun ti Ọlọrun ṣe fun wa ti ju ohunkohun ti ẹnikẹni ti ṣe si wa sẹyin lọ. Afojusun kan ṣoṣo ti a ni bayii ni lati mu ipinlẹ Ọṣun tẹsiwaju”

Gomina Adeleke gboriyin fun awọn ori-ade mejeeji fun ipa takuntakun ti wọn ko lori ọrọ ibo gomina naa, ati bi wọn ṣe duro gbagbaagba lẹyin oun ati idile rẹ.

O fi da awọn ọba naa loju pe oun ko ni i ja wọn kulẹ, o ni ni gbogbo ọna loun yoo ti mu idagbasoke ba ipinlẹ Oṣun ju bi oun ṣe ba a lọ.

Ninu ọrọ rẹ, Timi ti ilu Ẹdẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun to pada faaye gba Adeleke lati di gomina lẹyin ọpọlọpọ ogun to fi ọdun mejila ja, o si tun dupẹ lọwọ awọn eeyan ilu Ẹdẹ ati ipinlẹ Ọṣun lapapọ fun aduroti wọn.

Ọba Munirudeen Lawal rọ gomina lati ma ṣe dawọ iṣẹ rere to mu ki awọn araalu maa nifẹẹ rẹ to n ṣe duro, nitori oun naa fẹẹ ṣe baba gomina fun ọdun mẹjọ gbako.

 

Leave a Reply