Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ojiṣẹ Ọlọrun kan, Pasitọ Famakinwa Ajayi, ti gba idajọ ẹwọn ọdun mejidinlogun lati ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Akurẹ, latari ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan to jẹ ọmọ ayalegbe rẹ to fipa ba lo pọ ni nnkan bii ọdun meji sẹyin l’Ayede-Ọgbẹsẹ, n’ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.
ALAROYE gbọ pe Pasitọ ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun ni wọn lo fipa ba ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri naa sun lọpọlọpọ igba, titi to fi fun un loyun lọdun 2021.
Pasitọ Ajayi ni wọn fẹsun kan lọdun naa lọhun-un pe o ba ọmọbinrin to jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ijọ rẹ ọhun sun ninu palọ ile rẹ, ati ninu ọja nla to wa niluu Ọgbẹsẹ, laarin oru dudu.
Pasitọ ọhun jẹwọ nigba naa pe loootọ loun ba ọmọ ọlọmọ sun ninu palọ ile oun, ṣugbọn to ṣẹ kanlẹ pe oun ko ba a lo pọ laarin aarin ọjà loru.
O ni oun mu-un lọ saarin ọjà loootọ lati lọọ ṣeto awọn akanṣe adura kan fun un ni, ki i ṣe lati ba a sun.
Lẹyin-o-rẹyin ni wọn wọ pasitọ naa lọ sile-ẹjọ, nibi ti Agbefọba, Abilekọ Helen Falọwọ, ti fẹsun meji ọtọọtọ: ibalopọ aitọ pẹlu ọmọde ati lilo ọmọ nilokulo kan an.
Awọn ẹsun yii ni wọn lo ta ko abala kọkanlelọgbọn ati ikejilelọgbọn ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo, eyi to n daabo bo ẹtọ awọn ọmọde.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, Onidaajọ Yẹmi Fasanmi ni ko si aridaju ẹri pe olujẹjọ jẹbi ẹsun kejì ti i ṣe ẹsun lilo ọmọ nilokulo, ṣugbọn gbogbo ẹri ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ lo fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun akọkọ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, nu Onidaajọ Fasanmi ni oun da pasitọ naa lẹbi lori ẹsun kin-in-ni, eyi ti i ṣe nini ibalopọ aitọ pẹlu ọmọde. Lo ba ni ko tete lọọ fẹwọn ọdun mejidinlogun jura lori jijẹbi ẹsun naa.