Awọn ero to ba wọ mọto wọn lawọn eleyii n ja lole

Adewale Adeoye
Awọn ọdaran meji kan, Fọlaṣade Sholagbe, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, ati Ṣeun Ọkẹ, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ti wọn ti n ja awọn ara Eko lole latọjọ to pẹ lọwo tẹ l’Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lagbegbe Ikeja, nipinlẹ Eko.
Awọn ọdaran mejeeji naa ni wọn ti wa ninu ahamọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko bayii, ti wọn si n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn lati mọ ohun to sun wọn dedii iwa palapala naa.
Atẹjade kan to tọwọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Benjamin Hundeyin, jade sọ ọ di mimọ pe awọn ọlọpaa ikọ Iju ni wọn ṣe kongẹ ibi tawọn ọdaran naa ti n ja araalu kan lole owo ati dukia rẹ, ti onitohun si figbe ta pe ki awon eeyan to wa nitosi lọjọ naa gba oun silẹ lọwọ awọn ọdaran yii. A gbọ pe kia lawọn ikọ ọlọpaa ọhun bẹrẹ si i sare tẹle mọto Corrola kan bayii tawọn ọdaran naa fi maa n jale kaakiri aarin ilu Eko, ti wọn si ri wọn mu.
ALAROYE gbọ pe gbara tawọn ọdaran mejeeji naa ti gbe ẹyọ ero kan lẹgbẹẹ ileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣohun mimu ẹlẹrin-dodo ‘Seven up’, lojuna marosẹ Eko si Ibadan, ni wọn ti yọ ohun ija oloro si i, ti wọn si gba gbogbo dukia ọwọ rẹ pata, lẹyin eyi ni wọn le e bọ silẹ ninu mọto wọn, kia ni onitọhun paapaa si ti figbe ta, to ni kawon eeyan ti wọn wa lagbegbe naa ran oun lọwọ. Ọpẹlọpẹ awọn ikọ ọlopaa kan lati Iju, ti wọn wa nitosi ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni wọn sare tẹle awọn ọdaran naa, tọwọ si tẹ wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa Eko, ti ṣeleri pe lẹyin tawọn ba pari gbogbo iwadii awọn lawọn yoo gbe awọn mejeeji lọ si kootu.

Leave a Reply