Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ẹlẹ́rìn tilu Ẹ̀rinlé, nijọba ibilẹ Ọyun, nipinlẹ Kwara, Ọba Ibrahim Ajibọla Olusookun, ti darapọ mọ awọn baba nla rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Karun-un yii.
Alaga kansu ijọba ibilẹ Ọyun, Dokita Waheed Ibrahim, lo kede iku ọba alaye naa lọsan-an ọjọ yii, to si lawọn maa kede bi eto isinku ọba alaye naa yoo se lọ laipẹ.
Ilu Ẹrinle lo paala pẹlu Ọffa. Kabiyesi gori oye lọdun 1982, to si lo ọdun mọkanlelogoji lori apere awọn baba nla rẹ ko too di pe o faye silẹ.
Awọn mọlẹbi ko ti i sọrọ lori eto isinku atawọn nnkan mi-in to yẹ ni ṣiṣe.