Agunbanirọ at’awọn ọdọ mẹtalelogun dero atimọle EFCC n’Ibadan, Yahoo ni wọn n ṣe

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi agunbanirọ ṣe jẹ ẹni to n ṣiṣẹ sin orile-ede rẹ lẹyin to ti kẹkọọ jade nileewe giga, ti ẹni to n ṣẹwọn lọwọ paapaa si jẹ ẹlẹṣẹ to n ṣiṣẹ sin ilẹ baba ẹ gẹgẹ bii ijiya ẹṣẹ, ọna mejeeji teeyan n gba sìn ilẹ baba ẹ lo ṣee ṣe ki ọmọkunrin agunbanirọ kan ṣe akanpọ rẹ bayii pẹlu bo ṣe n rin ni bebe ẹwọn.

Agunbaniro yii, Ogundahusi Victor Damilare,

pẹlu awọn mẹtalelogun (23) mi-in lọwọ ajọ EFCC tẹ fun ẹsun jibiti lilu lori ẹrọ ayelujara.

Nigba to n fìdi iroyin yii mulẹ fawọn oniroyin ninu atẹjade to fi ṣọwọ si wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, Alukoro ajọ EFCC, Ọgbẹni Wilson Uwujaren, sọ pe ki i ṣe oju kan naa lawọn agbofinro ti ri awọn mẹrẹẹrinlelogun (24) mu, niṣe ni wọn n lọọ ka wọn mọ ibi ti kaluku wọn fara pamọ si lọkọọkan ejeeji lẹyìn ti awọn eeyan ti ta wọn lolobo nipa wọn.

.Orukọ diẹ ninu wọn ni Habeeb Lawal Abdulateef, Jaiye Gbọlahan Emmanuel, Giwa Usman Dọlapọ, ati Ọlawale Tosin Ṣẹgun.

O ni awọn eeyan wọnyi ko ni iṣẹ mi-in ti wọn n ṣe ju ki wọn maa purọ tan awọn eeyan jẹ, ki wọn si maa gbowo nla nla lọwọ wọn lọ.

Ọkọ ayọkẹlẹ olowo nla ti marun-un ninu awọn afurasi ọdaran yii fi n jaye kiri lajọ EFCC gba lọwọ wọn nigba ti apapọ foonu ti wọn ti gba lọwọ gbogbo wọn jẹ marundinlogoji (35).

Lara awọn nnkan olowo nla ti ajọ EFCC tun gba lọwọ wọn ni aago olowo iyebiye marun-un

Laipẹ yii ni wọn yoo foju awọn eeyan naa bale-ẹjọ gẹgẹ bi Uwujaren ṣe fìdi ẹ mulẹ.

Leave a Reply