Awọn dokita orileede Saudi-Arabia fiṣẹ abẹ ya ibeji ilẹ wa ti wọn lẹ pọ

Monisọla Saka

Awọn ibeji ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan ti wọn lẹ papọ latigba ti wọn ti bi wọn, Hassanah ati Husseina, lawọn akọṣẹmọṣẹ dokita oniṣẹ abẹ ti pin wọn niya, tonikaluku wọn si ti da wa gẹgẹ bo ṣe yẹ ki wọn wa, lẹyin iṣẹ abẹ to gba odidi wakati mẹrinla, lorilẹ-ede Saudi Arabia, eyi ti wọn bẹrẹ ẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Awọn ibeji ọmọ ọdun kan ọhun, ti idodo, ẹgbẹ inu, ẹdọ, ifun, ile itọ ati gbogbo awọn ẹya ara to n ṣiṣẹ fọmọ bibi lagọọ ara eeyan wọn lẹ papọ, ti wọn si jọ n lo o papọ yii, ni wọn bi niIe iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ileewe giga Ahmadu Bello University Teaching Hospital, niluu Kaduna, lọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2022.

Lẹyin ti wọn bi awọn ọmọ yii tan, ti wọn si ri ipo ti wọn wa, ni wọn dari wọn lọ si ile iwosan ijọba apapọ to wa niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu orilẹ-ede yii. Amọ to jẹ pe ko si eto iṣẹ abẹ tabi nnkan kan to le mu ayipada rere ba ipo tawọn ọmọ naa wa, nitori aisi owo. Eyi lo mu ki ijọba ilẹ Saudi dide iranwọ fawọn ẹbi naa  pe awọn yoo ṣiṣẹ abẹ fawọn ọmọ naa, lai gba kọbọ.

Awọn akọṣẹmọṣẹ igbimọ dokita ẹlẹni marundinlaaadọrun-un, ni wọn pawọ-pọ ṣe ipele meje akọkọ ninu mẹjọ iṣẹ abẹ tawọn ọmọ ọhun nilo lati wa lalaafia nile iwosan nla to jẹ tawọn ọmọde, King Abdullah Specialist Hospital for Children, lagbegbe ti ile iwosan loniran-n-ran pọ si, ti wọn n pe ni King Abdulaziz Medical City lorilẹ-ede Saudi Arabia.

Lọjọruu,Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, nijọba ilẹ Saudi buwọ lu iwe eto irinna awọn obi ọmọ yii pẹlu awọn ibeji ti wọn di pọ ohun, ti wọn si gbera lọ sorilẹ-ede naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila, ọdun 2022. Ọkọ oju ofufuru ileeṣẹ eto ilera ni wọn waa fi gbe wọn.

Gẹgẹ bi iroyin ilẹ Saudi kan, Arab News, ṣe sọ, o ni ileeṣẹ to n ri si igbaye-gbadun awọn eeyan nilẹ Saudi, ti ṣeranwọ lori aisan to jẹ mọ ki awọn ọmọ lẹ pọ tabi ni aleebu mi-in, to to bii aadoje, lati orilẹ-ede mẹtalelogun, lati nnkan bii ọdun mẹtalelọgbọn titi di isinyii. Ati pe ti Hassanah ati Husseinah, ni yoo jẹ awọn ibeji ẹlẹẹkẹrindinlọgọta, ti wọn yoo ṣe iru iṣẹ abẹ bẹẹ fun.

Ki wọn too bẹrẹ iṣẹ abẹ ọhun, ni Dokita Abdullah Al-Rabeeah, to jẹ olori ikọ awọn dokita oniṣẹ abẹ naa, to tun jẹ oludamọran fun igbimọ ọba ilẹ Saudi, ati alaamoojuto agba fun awọn igbimọ to n ri si igbaye-gbadun awọn eeyan, King Salman Humanitarian Aid and Relief Centre, ti sọ pe ipele mẹjọ, ni iṣẹ abẹ naa da le lori.

Nigba ti wọn pari awọn ipele iṣẹ abẹ yii, ti gbogbo rẹ si kẹsẹjari, aṣoju ilẹ Naijiria lorilẹ-ede Saudi Arabia, Yahaya Lawal, dupẹ pataki lọwọ awọn adari ilẹ Saudi fun iwa ẹlẹyinju aanu wọn lori awọn ibeji ti wọn lẹ pọ ọhun. O ni, “Mo fi akoko yii tun dupẹ si i lọwọ alakooso awọn mọṣalaṣi nla mejeeji, ọba ati gbogbo awọn aṣaaju ilẹ Saudi, fun ọwọ aanu ti wọn na si awọn ibeji ọmọ ilẹ Naijiria, Hassanah ati Hassina, ti wọn lẹ papọ latigba ti wọn ti bi wọn.

“Inu ilẹ Naijiria ni pataki ju lọ dun, lati ri ọjọ oni, inu temi paapaa naa si dun. A tun dupẹ pupọ lọwọ dokita Al-Rabeeah, ati gbogbo awọn ikọ ti wọn lọwọ ninu iṣẹ abẹ ẹlẹgẹ yii.

Ki Ọlọrun bukun fun wọn, akitiyan wọn, ilẹ Saudi ati gbogbo awọn eeyan ilẹ Saudi patapata. Titi laelae nilẹ Naijiria yoo maa dupẹ oore tẹ ẹ ṣe yii.

Leave a Reply