Awọn agbẹjoro mi yoo tu aṣiri eru to wa lasiko ibo aarẹ-Atiku

Adewale Adeoye

‘Pe ileejọ to ga ju lọ lorileede yii,  Supreme Court, da ẹjọ ti mo pe lori Alhaji Kasim Shettima, igbakeji ẹni ti wọn yan sipo aarẹ ilẹ yii pe ko lẹtọọ lati tun dupo kankan mọ lorileede yii, niwọn igba to ti le gba fọọmu oriṣii meji ọtọọtọ lati dupo ninu ibo to waye gbeyin, tileẹjọ si sọ pe ẹjọ mi ko lẹsẹ nilẹ, ti wọn si da a nu, eyi ki i ṣopin ohun gbogbo fun mi rara. ‘‘A ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, laipẹ, gbogbo rẹ pata ni yoo foju han kedere pe emi  ni mo wọle’. Eyi lọrọ ti ondije dupo aarẹ orileede yii lẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubarkar, sọ nileẹjọ, lẹyin tawọn adajọ to n gbọ ẹjọ to pe pe ki wọn fagi le Alhaji Shettima, igbakeji Tinubu ti wọn yan gẹgẹ bii aarẹ orileede yii ninu ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii.

Ẹsun ti wọn tori ẹ gbe gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ naa lọ si kootu ni pe ẹẹmeji ọtọọtọ lorukọ Alhaji Shettima han pe o gba fọọmu lati dupo pataki lorileede yii, eyi ti ofin ilẹ wa ko faaye gba a rara.O ti kọkọ gba fọọmu ileegbimọ aṣofin agba, o si tun dije dupo igbakeji gomina, eyi ti ko ba ofin ilẹ wa mu.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, nileẹjọ to ga ju lọ nilẹ yii, eyi to wa niluu Abuja, wọgi le ẹjọ ti Atiku pe Shettima. Wọn ni ẹjọ rẹ ko lẹsẹ nilẹ rara, ati pe niwọnba igba ti Atiku ki i ti ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ko laṣẹ rara labẹ ofin ilẹ wa lati yọju si bi wọn ti ṣe n ṣakooso ẹgbẹ wọn.

Ṣao, Atiku ti ni idajọ to waye lọjọ Ẹti naa ki i ṣopin ohun gbogbo rara, nitori ikọ awọn agbẹjọro oun ti ni awọn ẹri to daju daadaa lọwọ lati fi han awọn adajọ ti wọn maa gbọ ẹjọ toun pe lori bi eru ṣe wa lakooko ibo aarẹ ilẹ yii to waye loṣu Keji, ọdun yii.

Atiku ni ‘ Ohun to da mi loju daadaa ni pe mo ni awọn agbẹjọro to kunjun oṣuwọn daadaa to  maa fi ye awọn adajọ to n gbọ ẹjọ ti mo pe lori pe eru wa ninu ibo aarẹ to gbe Tinubu wọle, bi akoko ba to, gbogbo eeyan naa ni wọn yoo foju ara wọn ri i. Idajọ awọn adajọ to wọgi le ẹjọ ti mo pe Alhaji Shettima yii ki i ṣohun toju kori ri, a ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, awọn agbẹjọro mi ti fi da mi loju pe ma a bori lopin ohun gbogbo’.

Leave a Reply