Adewale Adeoye
Awọn ọlọpaa agbegbe Asaba, nipinlẹ Delta, ti mu mẹrin lara awọn ọdaran kan ti wọn maa n lo motọ wọn lati fi ja awọn araalu lole dukia wọn eyi ti wọn n pe ni ‘One Chance’
ALAROYE gbọ pe lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni awọn ọdaran naa ja ọgbẹni kan tawọn ọlọpaa ko darukọ rẹ sita lole dukia rẹ lojuna Benin si Asaba, lẹgbẹẹ papakọ ofurufu to wa niluu naa. Gbogbo ohun ti ọgbẹni naa ko dani ni wọn gba lọwọ rẹ pata, ti wọn si sa lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, S.P Edafe Bright, to n ṣafihan awọn ọdaran naa fawọn oniroyin lọsẹ to kọja sọ pe, awọn kan ni wọn waa ṣofoofo fawọn ọlọpaa kan, ti ọga agba ikọ ọlọpaa RRS, ASP Julius Robinson, si ko awọn ọmọoṣẹ rẹ lọọ koju wọn nibi ti wọn wa, tọwọ si tẹ Ọgbẹni Ananias Omachefu, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, to jẹ ọmọ ipinlẹ Kogi, ṣugbọn to n gbe lagbegbe Okwe, niluu Asaba, nipinlẹ Delta. Lẹyin tọwọ tẹ ẹ tan lo gba lati mu awọn ọlọpaa lọ sibi tawọn yooku rẹ wa lagbegbe Abraka. Ninu ọja Abraka naa ni ọwọ wọn ti tẹ olori ikọ awon ọdaran naa torukọ rẹ n jẹ Chinedu Sunday, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn. Lẹyin tọwọ tẹ olori ikọ naa tan lo gba lati mu awọn ọlopaa ọhun lọ sibi ti wọn maa n ko gbogbo ẹru ti wọn ba ji gbe si, nibẹ naa ni wọn ti ba awọn dukia ẹni ti wọn ja lole naa, ti wọn si gba gbogbo ẹ lọwọ wọn patapata.
Alukoro ọhun ni awọn ọlọpaa ko ni i ye fọwọ ofin mu gbogbo awọn ọdaran naa, afi ki wọn filu naa silẹ lo maa daa.