Adewale Adeoye
Awọn agba bọ wọn ni ọrọ ti oloko fi n sẹkun sun ni aparo fi n ṣẹrin-rin, bẹẹ gan-an lọrọ ri fun Ọgbẹni Kọlade Thompson, to mu ẹjọ iyawo rẹ, Abilekọ Taiwo Thompson, lọ si kootu kọkọ-kọkọ kan to wa lagbegbe Mapo, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ. Bi baale ile yii ṣe n sunkun rojọ niwaju adajọ ileejọ naa nitori bọrọ ọhun ṣe ka a lara lawọn to wa ni kootu n rẹrin-in.
Pẹlu omije loju ni Kọlade fi n rojọ niwaju Onidaajọ S.M Akinyayọ. O ni ọrọ iyawo oun yii ti sun oun patapata, ki adajọ jọwọ tu igbeyawo ọlọdun gbogbọrọ to wa laarin awọn mejeeji ka, ki onikaluku maa lọ lọtọọtọ.
Nigba ti baale ile yii ba ọrọ rẹ debi kan, niṣe lo tun bu sẹkun gbaragada. O ni ohun to n dun oun ju ninu ọrọ iyawo oun yii ni pe bii ọrọ lo ṣe maa n rinde oru rẹ ti pọ ju, oun ko si le fara da a mọ. O fi kun un pe toun ba de lati ibiiṣẹ, dipo ki iyawo oun tete lọọ dana ounjẹ toun atawọn ọmọ maa jẹ, ṣe ni yoo tun ki foonu rẹ mọlẹ, ti yoo si maa pe awọn ọrẹkunrin rẹ gbogbo lọganjọ oru.
Ẹsun yii atawọn mi-in ni Kọlade ro papọ to fi sọ pe oun ko ṣe mọ rara, o ni ki adajọ tu igbeyawo to wa laarin awọn mejeeji ka kiakia, ki wọn si gba oun laaye lati maa tọju awọn ọmọ mẹtẹẹta to wa laarin awọn, nitori pe iyawo oun yii ko ni aaye rara lati maa ṣetọju awọn ọmọ naa bo ba le gba wọn sọdọ.
Kọlade ni, ‘Mo ṣe suuru gidi pẹlu iyawo mi ni o, bi wọn ba n wa pa-mi-n-ku ti i ṣori bẹnbẹ sọkọ, oun ni, ki i le ṣetọju mi rara ninu ile, ọpọ igba lo jẹ pe emi ni ma a lọọ mu awọn ọmọ wa lati ileewe wọn, emi ni maa tun ṣeto ohun ti wọn maa jẹ bi wọn ba de lati ileewe, bi mo ba si sọrọ bayii, ṣe ni yoo gbeja ko mi loju loju-ẹsẹ. Lara pe ko fẹẹ ri ẹnikankan mọ mi lo ṣe le iya to bi mi lọmọ lọ, iya mi ki i lee dele mi mọ, o tun ti ko ba mi lọdọ awọn ọrẹ mi gbogbo, tawọn yẹn paapaa ki i wa sọdọ mi mọ rara bayii.
Ninu ọrọ tiẹ, Abilekọ Taiwo Thompson, ni ko sootọ kankan ninu ẹsun ti ọkọ oun fi kan oun yii rara, ṣao, Taiwo gba pe loootọ loun ti figba kan lu gilaasi ọkọ rẹ fọ nigba to fẹẹ pa oun lọjọ kan bayii.
Taiwo ni, ‘‘Ẹranko gbaa lọkọ mi yii, irọ si ti pọ ju ninu ẹjọ wẹwẹ to waa ro nile-ẹjọ yii, emi kọ ni mo le iya rẹ nile rara, ko wu iya naa mọ lati maa wa sile wa ni ko ṣe wa mọ, ojoojumọ ni ọkọ mi fi maa n lu mi bii baara, maaluu to kẹyin sọdọ awọn Fulani paapaa ko jiya to mi rara.
‘‘Emi paapaa ko ṣe mọ o, ohun kan ti ma a bẹ ẹ fun ni pe ko jẹ ki n ko awọn ọmọ mi yii sọdọ, ki n le maa ṣetọju wọn daadaa. Nigba ti mo kọkọ ko ẹru mi diẹ jade nile rẹ, mo mu awọn ọmọbinrin meji ti mo bi fun un pẹlu mi, mo si fi ọkunrin kan ṣoṣo silẹ fun un pe ko maa ṣetọju rẹ lọ, ṣugbọn ṣe lo waa fipa gba ọmọ naa lọwọ mi, ohun to sọ ni pe ki n ko awọn ọmọ naa wa sọdọ oun, o loun fẹẹ foju kan wọn. Bi mo ṣe ko awọn ọmọ naa wa lo ti sọ pe mi o le ko wọn pada mọ, o ti paarọ ileewe wọn, ki i gba mi laaye lati foju kan wọn mọ, mo lọọ sọ fawọn ọlọpaa, wọn ko rohun gidi kan ṣe si i, ohun ti wọn sọ ni pe niwọn igba ti ọrọ wa ti dele-ẹjọ, ko sohun tawọn maa ṣe si i.
‘‘Ẹbẹ ti mo n bẹ bayii ni pe kile-ẹjọ paṣẹ fun ọkọ mi yii pe ko faaye gba mi lati ko iwọnba ẹru mi to ku nile rẹ, ko si jẹ ki n maa ṣetọju awọn ọmọ mi lọ’’.
Adajọ Abilekọ S.M Akinyayọ ti sun igbejọ awọn tọkọ-taya mejeeji yii sọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.