Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti kede Alhaji Mukaila Lamidi, olori ẹgbẹ awọn awakọ ero nipinlẹ naa gẹgẹ bii ogbologboo afurasi ọdaran eeyan ti wọn n wa, ọkunrin tawọn eeyan tun mọ si Baba Riliwana, ṣugbọn ti gbogbo aye tun mọ si Auxiliary, ti fọwọ sọya pe awọn agbofinro ko le mu oun.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni CP Adebọwale Williams, ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ yii kede Auxiliary gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa fun ẹsun ipaniyan, idigunjale atawọn iwa ọdaran mi-in loniran-n-ran.
Tẹ o ba gbagbe, ni kete ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti kede pe oun ko fẹẹ ri igbimọ alaṣẹ awọn awakọ naa mọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lawọn ẹmẹwa ọkunrin naa ti n da igboro ru lojojumọ pẹlu ibọn yinyin, ti awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn pẹlu ibẹru bojo.
Awọn agbegbe ti wahala ọhun ti bẹrẹ lati irọlẹ ọjọ Mọnde ọhun ni Iyana-Church, Alakia, Iṣẹbọ ati Iwo-Road, ko too di pe wọn tun ṣe kinni ọhun wọ awọn agbegbe bii Apata, ti wọn si tun tẹsiwaju ninu ifigagbaga ibọn yinyin naa laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un ọdun yii.
O kere tan, eeyan bii marun-un l’ALAROYE gbọ pe wọn ṣe bẹẹ yinbọn pa lagbegbe Iwo Road nikan, laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ (30), oṣu Karun-un, ọdun yii nikan.
Nitori awọn rukerudo lọtun-un-losi ti wọn sọ pe ọga awọn awakọ ero yii pẹlu awọn ọmoogun ẹ n da silẹ lo mu ki awọn ọlọpaa ṣigun lọ sileetura ẹ, ‘Diamond Hotel’, to wa laduugbo Alakia, n’Ibadan, nibi ti awọn ẹruuku ti jagunlabi maa n ko lẹyin kaakiri ti fìja pẹẹta pẹlu wọn fun ọpọlọpọ wakati, ko too di pe apa awọn agbofinro papa ka wọn nigbẹyin.
Oriṣiiriṣii ibọn ti apapọ wọn jẹ mẹtadinlọgọfa (117) lawọn ọlọpaa lawọn ba ninu ile nla ọhun pẹlu awọn nnkan ija bii ada, ọbẹ ati ọpọlọpọ oogun abẹnu gọngọ. Bẹẹ ni wọn ba owo to le ni miliọnu mẹta Naira nibẹ pẹlu awọn ọkọ bọọsi ati ọkọ ayọkẹlẹ bii meloo kan.
Mejidinlọgọrin (78) ninu awọn ọmọ ẹyin ọkunrin afurasi adaluru yii lawọn ọlọpaa ti mu bayii, ti wọ si ti kede pe awọn yoo mu Auxiliary naa nibikíbi ti awọn ba ti ri i.
Ṣugbọn lori eto ori redio aladaani kan to waye n’Ibadan l’Auxiliary funra rẹ ti ba awọn atọkun eto naa sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ pe awọn ọlọpaa ko le mu oun, nitori Gomina Makinde gan-an lalatilẹyin oun.