Faith Adebọla, Eko
Bawọn kan ṣe n kawọ leri, ti wọn n fẹsẹ janlẹ, bẹẹ ni igbe oro ati idaro gba ẹnu awọn mi-in, latari ijamba to waye lafẹmọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibi ti ọkọ reluwee ti ka mọto meji mọ oju irin rẹ, to run awọn mọto naa womuwomu, to si ṣeku pa tọkọ-taya kan loju ẹsẹ.
ALAROYE gbọ pe tọkọ-tiyawo kan lo wa niwaju mọto Toyota Sienna ti nọmba rẹ jẹ LAGOS FST-723-FL, wọn ni wọn tete ji de iwaju ọja igbalode Nigeria Army Shopping Arena to wa ni ibudokọ Bọlade, wọn fẹẹ wọ inu ọja naa lati bẹrẹ kara-kata wọn.
Gẹgẹ bi ọlọpaa kan, S. A. Buladima, ṣe ṣalaye f’ALAROYE, o ni mọto meji ni reluwee to ṣe yọ lati ọna Ikẹja naa ka mọ oju irin rẹ, mọto kan ti tọkọ-taya yii wa ninu rẹ ati ekeji to ko awọn ero bii mẹjọ.
Latokeere ni reluwee naa ti n fọn fere rẹ leralera, ṣugbọn ko ṣee ṣe fun eyikeyii ninu awọn ọkọ ọhun lati sare kuro, tori ọgangan oju irin naa lawọn mejeeji wa, awọn ọkọ mi-in si ti di wọn mọ niwaju ati lẹyin wọn.
Ori ko dirẹba mọto keji ati awọn ero to wa ninu rẹ yọ nitori o ṣee ṣe fun wọn lati bẹ danu bi reluwee naa ṣe sun mọ itosi wọn, mọto nikan ni wọn ko raaye gbe kuro.
Ṣugbọn wọn ni ibi ti ọkunrin tiyawo rẹ jokoo ṣẹgbẹẹ rẹ ninu mọto keji ti n ṣe akitiyan boya mọto rẹ yoo raaye kuro ni reluwee ka wọn mọ, oju ẹsẹ lawọn mejeeji si ti doloogbe.
Womuwomu ni reluwee naa run awọn ọkọ mejeeji, o si wọ ọkan lara ọkọ naa lati Bọlade de abẹ biriiji Oṣodi ko too duro.
Nigba ti akọroyin debi iṣẹlẹ naa, wọn ni awọn ẹṣọ alaabo oju popo ti gbe oku awọn mejeeji naa lọ si mọṣuari.
Titi di akoko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ko ti i sẹni to mọ orukọ tabi adiresi awọn to doloogbe naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ni inu ọja igbalode naa ni wọn ti n taja.