Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn aṣofin ipinlẹ Ọṣun ti yan ọkan lara wọn, Adewale Ẹgbẹdun, lati ijọba ibilẹ Odo-Ọtin, gẹgẹ bii olori ile naa.
Ọkan lara wọn, Ọnarebu Ibrahim Abiọla, lati agbegbe Irewọle/Iṣọkan lo dabaa pe ki wọn lo Ẹgbẹdun, nigba ti Ọnarebu Areoye Samuel ṣikeji rẹ.
Ọmọ bibi ilu Aṣhi, ni Adewale, akọṣẹmọṣẹ ninu eto ọgbin ni, ọmọ ọdun mejidinlogoji pere lọmọkunrin naa, igba akọkọ ti yoo si wa sileegbimọ aṣofin niyi.