Adewale Adeoye
Awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba orileede yii ti fontẹ lu u pe ki Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, gba awọn olubadamọran ogun ti yoo ba a ṣiṣẹ, ki ohun gbogbo le rọrun fun un gẹgẹ bi ohun to sọ fun wọn.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni Olori ileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa, Ahmad Lawan, ka lẹta pataki kan ti wọn ni Aarẹ Tinubu kọ ranṣẹ sileegbimọ naa, nibi to ti n bẹ wọn pe ki wọn faaye gba oun lati gba awọn olubadamọran ogun, ki wọn le maa b’oun ṣiṣẹ pọ.
Gbara ti wọn ka lẹta ọhun setiigbo gbogbo awọn aṣofin naa ni Sẹnetọ Ibrahim Gobir, to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, to n ṣoju agbegbe Sokoto East, ti n gbawaju, to n gbẹyin, to si n sọ fawọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku pe ki wọn tete fontẹ lu lẹta naa, ki Aarẹ Tinubu le gba awọn olubadamoran yii ni kia, ki wọn le tete bẹrẹ iṣẹ ilu fun Aarẹ Tinubu.
Yatọ si Sẹnetọ ọhun to loun faramọ lẹta naa, Sẹnetọ Philip Aduda ti i ṣe olori kekere (Minority Leader) naa loun paapaa faramọ aba Aarẹ Tinubu yii.
Lẹyin gbogbo atotonu awọn aṣofin ọhun ni wọn fontẹ lu u pe ki Aarẹ lọọ gba awọn olubadamọran ogun to loun fẹẹ gba fun iṣẹ ilu naa, ki gbogbo nnkan le maa lọ deede fun iṣakooso ijọba rẹ.