Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti ṣepade bonkẹlẹ kan pẹlu awọn gomina marun-un kan ti wọn ko ṣatileyin fun oludije wọn sipo aarẹ lẹgbẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar lasiko ibo to waye loṣu Keji, ọdun yii, ni ọfiisi rẹ l’Abuja, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Awọn gomina maraarun ọhun ni Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ, gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Ọgbẹni Nysome Wike, gomina ipinlẹ Benue tẹlẹ, Ọgbẹni Samuel Ortom, gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ, Ọgbẹni Okezie Ikpeazu ati gomina ipinlẹ Enugu tẹlẹ, Ọgbẹni Ifeanyi Ugwuanyi.
Nigba to n sọrọ nipa idi pataki ti wọn fi ṣabẹwo naa, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, to gbẹnu awọn eeyan naa sọrọ ṣalaye pe gbigbe orileede ro ki i ṣe iṣẹ kekere, nitori idi eyi, eeyan gbodọ maa ṣe agbeyẹwo aṣetunṣe lori ohunkohun to ba n ṣe, ati ibi to n lọ.
‘‘O ṣẹ pataki lati ri Aarẹ, lati jẹ ko mọ ohun to n lọ. Koko ohun to si gbe awa gomina maraarun ta a duro fun ohun to daa yii wa sọdọ Aarẹ Tinubu ni pe a duro fun ohun to tọ, to si yẹ, eyi ti ko ni irẹjẹ ninu, a ko si ti i yẹ kuro lori eleyii’’.
O fi kun un pe o ṣe pataki ki Aarẹ maa gbọ nipa ohun to n lọ ni oriṣiiriṣii ọna, ko ma lọọ di pe awọn kan yoo fọwọ digaga rẹ, ti ko fi ni i mọ ootọ ohun to n lọ tani to n ṣẹlẹ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹrin kọja ọgun iṣẹju ni awọn eeyan naa de si ọfiisi Aarẹ Tinubu, ti wọn si wọle lọọ ba a taarata nibi to ti n duro de wọn.
Bẹ o ba gbagbe, igba kẹta ree ti Wike yoo lọọ ṣabẹwo si Aarẹ Tinubu ni ọfiisi rẹ niluu Abuja latigba ti gomina Eko tẹlẹ naa ti di olori orileede wa.
Bakan naa ni ki i ṣohun to bo rara pe awọn gomina maraarun-un yii ni wọn ṣiṣẹ ta ko ọmọ ẹgbẹ wọn to dije dupo aarẹ ilẹ wa ninu ibo to waye lorileede yii lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
Igbagbọ awọn eeyan ni pe Tinubu lawọn gomina yii ṣiṣẹ fun.