Ọkọọyawo yari: Emi kọ ni mo lọmọ tiyawo mi gbe lọwọ yẹn o- Salisu

Adewale Adeoye

Ọrọ kọja bẹẹ nile-ẹjọ Sharia kan to wa lagbegbe Magajin-Gari, nipinlẹ Kaduna, nibi ti baale ile kan, Ọgbẹni Samaila Salisu, ẹni ọdun mejidinlogoji, gbe iyawo rẹ, Abilekọ Mary Ibrahim, lọ, to si ni ki adajọ ileẹjọ yii tu igbeyawo awọn kan. Ọkunrin naa to n sọro, to si fẹẹ maa sunkun sọ pe ki i ṣoun loun ni ọmọ kan bayii ti iyawo oun gbe lọwọ, ko yaa tete wa ẹni to ba lọmọ lọ, ko si gbe e fun un.

Baale ile yii ni ẹẹmẹfa pere loun ba a lajọṣepọ latigba tawọn ti fẹra gẹgẹ bii lọkọ-laya lati 2022 to koja yii. Fun idi eyi, Salisu ni ki Adajọ Malam Isiyaku Abdulraman tu igbeyawo naa ka loju-ẹsẹ, ki obinrin naa si lọọ gbe ọmo fọlọmo.

Salisu ni, ‘Loni-in-ni ti igbẹjo waye nile-ẹjọ ni mo ṣẹṣẹ n gbọ pe iyawo mi ti bimọ, mo ni ẹlẹrii to daju pe emi kọ lo lọmọ to wa lọwọ rẹ yii rara. Lati inu oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 to koja yii, niyawo mi ti kẹru rẹ jade ninu ile ta a jo n gbe. Ko si too kẹru kẹru jade naa, ẹẹmẹfa pere ni mo ba a sun,  koda, mi o fi gbogbo ara gbadun ibasun naa, ṣugbọn mo gba pe, ẹẹmẹfa ni mo lajọṣepọ pẹlu rẹ. Gbogbo akitiyan mi lati jẹ ko pada wa sile nigba to kẹru jade lo ja si pabo, ṣe lo taku pe oun ko ni i pada wa sile mi mọ rara, o ṣe le waa gbe ọmọ ale ti mi o mọ nnkan kan nipa rẹ wa pe emi ni mo lọmọ naa bayii, irọ ni o, emi kọ lo lọmọ ọwọ rẹ yii o.

Ṣugbọn ninu ọrọ Abilekọ Mary, iyaale ile naa loun ko deede kẹru oun jade ninu ile toun ati ọkọ oun jọ n gbe yii, ṣugbọn nigba ti iya ti Salisu fi n jẹ oun pọ ju loun sa jade nile naa fun un.

Mary ni, ‘Ṣe ni Salisu maa n febi pa mi nigba gbogbo, ki i bikita rara ohun nipa ti ma a jẹ, ogi pẹlu ṣuga lasan ni mo maa n mu nigba gbogbo, ẹẹkọọkan ni mo maa n jẹ awọn ounjẹ ajẹku kan ti Salisu ba gbe wa lati ita fun mi. Ibi ti Salisu fẹ mi si jinna sibi tawọn eeyan mi wa, ko rọrun rara fun mi lati maa foju kan awọn ebi mi nigba gbogbo. Loootọ mo ti kẹru jade nile Salisu, ṣugbọn o ṣi maa n waa ba mi nibi ti mo wa lẹẹkọọkan, to si maa n ba mi lajọṣepọ daadaa ko too pada sile rẹ.

Adajọ Malam Isiyaku ti sun igbẹjọ naa siwaju, to si sọ fun Salisu pe ko mu ẹlẹrii to sọ nipa rẹ wa sileejọ lati fidii ọrọ rẹ mulẹ. O waa kilọ fun un pe ẹlẹrii naa gbọdọ sọ niwaju gbogbo eeyan ti wọn ba wa nileẹjọ naa pe oootọ lohun toun n sọ nipa Mary yii, bi bẹẹ kọ, ijiya nla lo wa fun Salisu ati ẹlẹrii rẹ bi oun ba mọ pe wọn n parọ ni.

Leave a Reply