Faith Adebọla
Tajudeen Abass, Ọnarebu to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Zaria, nipinlẹ Kaduna, lo gbegba oroke ninu eto idibo lati yan olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, iyẹn ileegbimọ aṣofin keji, l’Abuja.
Ṣibaṣiba lẹsẹ gbogbo awọn aṣoju-ṣofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan pe sileegbimọ wọn ọhun laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, aṣofin kan ṣoṣo, iyẹn Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, nikan ni ko si laarin awọn aṣọfin ọtalelọọọdunrun (360) tileegbimọ naa, lati yan awọn adari ti yoo maa tukọ iṣakoso wọn.
Awọn mẹta ni wọn dije fun ipo olori ile ọhun, bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn aṣoju-ṣofin naa ni wọn ti n gbe e pooyi ẹnu laarin ara wọn pe Abass lawọn maa ti lẹyin.
Nigba ti eto idibo naa fi maa pari, Abass ni ibo rẹ kun ju, gbọgbọọgbọ tọwọ n yọ ju ori si lo fi tayọ awọn oludije meji yooku pẹlu ibo ọtalelọọọdunrun din meje (353) ibo, nigba ti oludije keji, Ahmed Wase, ni ibo meji pere, ẹni kẹta, Sani Jaji, ko si ni ju ẹyọ ibo mẹrin lọ.
Niṣe lariwo idunnu sọ nigba ti wọn ṣi n ka ibo naa lọwọ, to si ti foju han pe Abass ni yoo wọle, latari bo ṣe tayọ oju ami ibo ti ẹni ti yoo jẹ olori ile naa gbọdọ ni, niṣe lo palẹmọ ibo naa patapata.
Bakan naa ni wọn tun yan Aṣofin Ben Kalu gẹgẹ bii igbakeji olori awọn aṣoju-ṣofin ọhun.
Ẹ oo ranti pe ALAROYE ti mu iroyin wa fun yin ṣaaju nipa bi wọn ṣe yan Godswill Akpabio, nileegbimọ aṣofin agba laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii kan naa, nigba to fẹyin Abdulazizz Yari janlẹ.
Ni bayii, Akpabio ati Abass ni yoo jọ tukọ ileegbimọ aṣofin apapọ, ẹlẹẹkẹwa iru rẹ to bẹrẹ yii, lasiko iṣejọba Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bii aarẹ ilẹ wa.