Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, ti kọ lẹta mi-in sawọn aṣofin ipinlẹ Ondo, ninu eyi to ti bẹbẹ fun gbigba aaye isinmi ọlọ́jọ́ mọkanlelogun lẹnu iṣẹ, ko le lanfaani ati mojuto ilera rẹ daadaa.
Ni ibamu pẹlu alaye ti olori ileegbimọ aṣofin ọhun, Ọnarebu Ọladiji Ọlamide, ṣe fawọn oniroyin ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lo ti fidi rẹ mulẹ pe lẹta ti Aketi kọ ti tẹ awọn lọwọ.
Ọladiji ni ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2023, ni aaye isinmi fun itọju ara rẹ naa ti bẹrẹ fun Gomina Akeredolu, ti yoo si wọṣẹ pada lọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun yii kan naa.
O ni ọlude ayajọ ọjọ ominira June 12 tijọba apapọ kede rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, àti aaye isinmi fun ọdun ileya to n bọ lọjọ kejidinlọgbọn si ikọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii kan naa lo ṣokunfa bi ọjọ ìwọlé pada sẹnu iṣẹ Arakunrin ṣe bọ si ọjọ kẹfà, oṣu Keje.
O ni Gomina Akeredolu tun ṣalaye ninu lẹta ọhun pe oun ti fa eto iṣakoso ijọba le Igbakeji oun, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, lọwọ, o ni ko maa dele de oun gẹ́gẹ́ bíi gomina titi ti oun yoo fi wọṣẹ pada lọjọ kẹfa, oṣu Keje.