Owọ Amọtẹkun tẹ ajinigbe kan l’Ondo, wọn tu ẹni ti wọn mu silẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn gende meji kan, Daisi Oloye ati ọrẹ rẹ, Monday John, lori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe to lọọ ka wọn mọ inu oko wọn to wa lagbegbe Oke-Oge, Ẹlẹ́yọwó, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

Ọkan ninu awọn ti ori ko yọ ọhun, iyẹn Oloye, sọrọ ilẹ kun lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nigba ti wọn n ṣafihan awọn afurasi ọdaran kan ni olu ileeṣẹ Amọtẹkun to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

O ni iṣẹ loun ati Monday n ṣe lọwọ ninu oko awọn ti awọn ọkunrin marun-un fi yọ si awọn lojiji, loju-ẹsẹ ti awọn ti ri wọn ni jinnijinni ti da bo awọn nitori ohun ti wọn tori rẹ wa ko kọkọ ye awọn rara.

Lojiji lo ni ọkan ninu wọn fa ada yọ, to si fẹẹ ṣa a mọ oun lori, ṣugbọọn ti oun yara fọwọ gba a ko too ba ori oun.

O loun nikan lawọn janduku maraarun-un ọhun kọkọ ṣuru bo nilẹ ibi ti oun ṣubu si, leyii to fun ẹni keji oun lanfaani lati raaye sa lọ, oun lo si lọọ fi iṣẹlẹ naa awọn eeyan leti.

O ni  awọn Amọtẹkun ni wọn pada waa gba oun silẹ lọwọ awọn ajinigbe ọhun lasiko ti wọn n mu oun wọnu igbo lọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, adari Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ, ni bi awọn ṣe n gba ipe pajawiri pe awọn oniṣẹẹbi tun ti ji awọn meji gbe lawọn ti sare mori le ọna ibẹ.

O ni ko pẹ rara tawọn fi ri ẹnikan ti wọn ji gbe gba pada lọwọ wọn, ti awọn si tun gbiyanju ati fi pampẹ ofin gbe ọkan ninu awọn ọdaran naa.

O ni ẹni tọwọ tẹ ọhun ti jẹwọ fawọn pe ajinigbe lawọn loootọ, ati pe awọn ẹgbẹ oun mẹrin yooku ti sa lọ, wọn si ti lọọ fara pamọ sibi kan lẹkun Guusu orilẹ-ede yii pẹlu awọn ibọn ọwọ wọn.

Adelẹyẹ ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lati ri awọn ọdaran ọhun mu nibi yoowu ti wọn le sa pamọ si ki wọn le waa foju wina ofin.

 

Leave a Reply