Adewale Adeoye
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa awọn akẹkọọ Fasiti Jos, nipinle Plateau meje kan ti awọn ajinigbe lọọ ka wọn mọ ibi ti wọn ti n kawe ninu ile kan ti awọn akẹkọọ ti ko gbe inu ọgba ileewe maa n gbe, ti wọn si ji meje ninu wọn gbe lọ lọjọ Iṣegun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa yii.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii ago kan oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, osu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lawọn ajinigbe ọhun ya wọ ile tawọn akẹkọọ yii n gbe to wa lagbegbe ‘Bauchi Ring Road’, nijọba ibilẹ Jos North, ti wọn sì ji meje lara awọn akẹkọọ ti wọn ba ninu yara lọjọ naa lọ patapata.
A gbọ pe, ṣe lawọn akẹkọọ ọhun n kawe lọwọ ni ipalẹmọ fun idanwo wọn to n lọ lọwọ. Awọn ajinigbe yii deede ya lu wọn, niṣe ni wọn fipa jalẹkun wọle, ti wọn si ji gbogbo wọn ko sa lọ.
Ọkan lara awọn akẹkọọ to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ nipa iṣẹlẹ naa sọ pe gbara tawọn ajinigbe naa ti wọnu yara awọn akẹkọọ naa ni wọn ti yọ ibọn si wọn, ti wọn si ko wọn wọnu mọto kan bayii ti wọn paaki siwaju ita ile naa.
Lọjọ keji ti i ṣe Ọjọbọ, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun yii lawọn akẹkọọ naa lọọ fọrọ ọhun to awọn alaṣẹ ileewe atawọn ọlọpaa agbegbe naa leti. Bakan naa ni wọn ti yan awọn kan lati ileewe ọhun wa pe ki wọn waa wo ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
ALAROYE gbọ pe awọn ajinigbe ọhun ti pe mọlẹbi ọkan lara awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe, ti wọn sì ti beere owo lọwọ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinle naa, D.S.P. Alfred Alabo, lawọn ti bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ awọn ajinigbe ọhun, o lawọn ti da ọlọpaa sinu igbo agbegbe naa boya wọn maa ri wọn mu.