Adewale Adeoye
Awọn mọlẹbi olori ẹgbẹ kan to n ja fun ominira ẹya Ibo, ‘Indigenous People Of Biafra’ (IPOB). Mazi Nnamdi Kanu, ti le awọn lọoya mejeeji to n ṣiṣẹ fun un danu bayii. Ẹsun ti wọn ka sawọn agbẹjọro ọhun lẹsẹ ni pe wọn kuna lati sa gbogbo agbara wọn lati yọ ọkunrin naa kuro lahaamọ awọn alaṣẹ ijọba orilẹ-ede Naijiria to wa latigba to ti wa lahaamọ naa.
Ọgbẹni Kanunta Kanu to jẹ aburo Nnamdi Kanu lo sọ eleyii di mimọ lori ẹrọ ayelujara l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii. Awọn agba lọọya mejeeji naa ni Ọjọgbọn Mike Ozekhome (SAN), ati Barisita Ifeanyi Ejiofor (SAN)
Alaye ti aburo Nnamdi Kanu se nipa igbesẹ ọhun ni pe ṣe lawọn lọọya ọhun kuna lati gba Nnamdi Kanu jade lahaamọ awọn DSS to wa niluu Abuja, latigba to ti wa nibẹ. Ẹsun miiran ti wọn tun fi kan wọn ni pe ṣe ni wọn tun da awọn dokita oniṣegun oyinbo kan to yẹ ko ṣetọju Nnamdi Kanu duro, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.
Kanunta ni, ‘Idi ta a ṣe gbaṣẹ lọwọ awọn looya naa ni pe, latigba ta a ti de lati kootu lọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni looya Mike Ozekhome ko ti yọju si Nnamdi Kanu lọgba ẹwọn to wa niluu Abuja.
Bakan naa lawọn lọọya mejeeji naa ko gba pe ki awọn dokita to yẹ kó lọọ ṣetọju ajijagbara yii lọgba ẹwọn to wa yọju si i lọjọ karun-un, oṣu yii, bo tilẹ jẹ pe Nnamdi Kanu ti sọ fun wọn lọjọ keji, oṣu yii pe, oun fẹẹ ri dokita oun. Ako mọ idi ti wọn ṣe gbe iru igbesẹ bẹẹ.
Fun awọn ohun ti wọn ṣe yii atawọn nnkan miiran ti wọn ti ṣe ṣaaju ti ko tẹ wa lọrun la ṣe da wọn duro bayii, ti a si maa gba awọn lọọya miiran lati ba wa yọ Nnamdi Kanu kuro lọgba ẹwọn to wa bayii.
Nipari ọrọ rẹ, Kanunta ti i ṣe ojulowo aburo Kanu dupẹ gidi lọwọ awọn lọọya naa fun gbogbo akoko ti wọn jọ fi ṣiṣẹ pọ, bakan naa lo sọ pe ki wọn tete juwọ awọn iwe atawọn ohun gbogbo to wa lọwọ wọn silẹ fun awọn mọẹbi loju-ẹsẹ.