Adewale Adeoye
Olori orileede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti sọ pe ondije dupo lẹgbẹ oṣelu ‘Labour Party’ (LP), ninu ibo aarẹ to waye lorileede yii lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, Ọgbẹni Peter Obi, ni oloṣelu ti gbogbo ọmọ orileede yii nilo, to le nu omije wọn nu patapata.
O ni bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ni wọn gbe ijọba ọhun fun lakooko yii, Obi loun gbagbọ pe o le gbe iṣakoso orileede yii de ebute ayọ lai si wahala kankan.
Ọbasanjọ sọrọ ọhun di mimọ lakooko to n ba oniroyin kan, Ọgbẹni Chude Jideonwe, sọrọ lori eto pataki kan laipẹ yii. Nibẹ ni baba ti wọn tun maa n pe ni Ẹbọra Owu naa ti ni Obi nikan loun gbagbọ pe o jẹ ojulowo oloṣelu pataki tawọn eeyan orileede yii nilo lakooko yii, to si le gbe iṣakoso ijọba wa de ebute ayọ.
Ọbasanjọ ni ‘Loju ti mo fi wo o, ba a ba n sọ nipa oloṣelu to mọ ohun to n ṣe, to le gbe orileede yii debute ayọ, Obi lọkan mi mu, oun si ni mo gbagbọ pe lo yẹ ki awọn ọmọ orileede yii nigbagbọ ninu rẹ pe, ko ṣejọba orileede wa lakooko yii.
Tẹ o ba gbagbe, latigba ti eto idibo naa ti fẹẹ waye ni aarẹ tẹlẹ naa ko ti fi bo pe gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ yii loun n satilẹyin fun lati di aarẹ ilẹ wa. Ọpọ igbesẹ lo si gbe lati ṣepolongo fun ọkunrin yii lọna kan abi omi-in, ko too di pe ipo naa ja mọ Aṣiwaju Tinubu lọwọ.
Titi di ba a ṣẹ n sọ yii ni ẹjọ ti Peter Obi pe Aarẹ tuntun naa ṣi wa niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ to suyọ lasiko idibo naa, ti ọkunrin yii si ti n ko ẹri oriṣiiriṣii kalẹ fawọn adajọ lati sọ pe oun loun bori ibo aarẹ naa.